Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams
Aarẹ ni mi, wọn ko gbọdo maa ti mi kaakiri nibi iwóde- Iba Gani Adams.
Ó lójú Ọba tó ju Aàrẹ ọna kakanfo lọ, ìdí tí n kò fi jáde ṣe Yoruba Nation Rally rèé- Iba Gani Adams
Iba Gani Adams to jẹ Aarẹ Ona Kakanfo gbogbo ilẹ Yoruba ṣalaye idi ti oun ko fi kopa ninu iwọde Yoruba Nations rally to waye ni ilu Eko lọjọ abamẹta to kọja lọ.
Ipo agba ni a n ba agba ni ibi ti ọrọ de duro, eeyan dẹ gbọdọ bọwọ fun ipo to ba dimu.
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Mo fẹ́ kí a dá Yorùbá Nations sílẹ̀ kí a lè máa mójútó àwọn adarí tó bá kọsẹ́ fúnra wa- Peter Fatomilola
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Gbogbo ìgbà ni Ooni Ogunwusi tí Ile Ife máa ń sọ̀rọ̀ Wolii TB Joshua pé....Olori Naomi Silekunola
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, others
Lori ọrọ ikọlu DSS si ile Sunday Igboho:
Iba Gani Adams bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbesẹ ikọ DSS lati ṣe ikọlu si ile Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho.
O ni pe eyi ko tọna rara si iwa ẹtọ ẹniyan pe ki DSS kọlu ile rẹ laarin oru ganjọ ki wọn pa eeyan to pọ ki DSS si tun gbe oku awọn eeyan naa lọ laiki n ṣe ole.
Ilé mi kọ́ ni àwọn DSS ti kó àwon ìbọ́n tí wọ́n pàtẹ- Sunday Igboho
- Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yoruba fọnmú lórí ìkọlù sílé Sunday Igboho
- Sunday Igboho kan sárá sáwọn ọmọ Yorùbá tó wọ́de lọ́jọ́ Sátidé, ṣùgbọ́n kò sọ ìdí tí kò fi jáde
- Àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé mi, mo fojú mi kòrókòró rí wọn - Sunday Igboho
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
Iba ni iṣẹlẹ ikọlu ile Sunday Igboho ba oun ninujẹ pupọ, koda o fa Naijiria sẹyin.
Iba sọrọ lori bi ọrọ Nnamdi Kanu ṣe ko ba orilẹede Kenya.
O ni DSS wọle bii ole lọ kọlu Sunday Igboho, ẹ tun palẹ oku mọ.

O ni: Sunday Igboho maa n sọrọ ju nigba mii bi emi funra mi lọpọ ọdun sẹyin gẹgẹ bii ọdọ.
Iba ni o yẹ ki iran yii maa lo ipo oun gẹgẹ bii aarẹ ni.

Oríṣun àwòrán, others
Lori ọrọ awọn Oba to lodi si Yoruba Nation:
Iba Gani Adams ni Oba Akanbi Oluwo ti ilu Iwo ati Oba Kuta nikan ni ọba ilẹ Yoruba to ṣi jade ṣe lodi si dida duro Oduduwa Republic bayii.
O ni awọn Oba to pọ lo wa lẹyin ijijangbara yii ṣugbọn wọn kan n fi ọgbọn ṣe e ni.
O ni awọn Oba yii n fi ipo agba wọn ṣatilẹyin to yẹ labele
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Sunday Igboho kìí ṣe ọmọ ìbàdàn, òun gan ló ń dá Ibadan ru, Auxilliary fún Sunday Igboho lésì
- Afurasí ‘Sọ́jà’ kọlu ilé Sunday Igboho lóru mọ́jú, òkú ṣùn, dúkìá bàjẹ́
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
Lori ọrọ igbesẹ Aarẹ Buhari lasiko yii:
Iba Gani Adams bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba aarẹ Buhari to n tukọ Naijiria lasiko yi.
O ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe awọn aṣiṣe to pọ.

Oríṣun àwòrán, others
O sọrọ lori apero CONFAB to waye sẹyin ti Aarẹ Buhari ti da awọn abajade ojutu siṣoro Naijira danu.
Iba ni kii ṣe 'Democracy'ni a n ṣe mọ́ ní Nàìjíríà.
O mẹnuba ọna abayọ si Oduduwa Republic ati bi ijọba Buhari ṣe n fiya jẹ ẹya kan ju ẹya mii lọ



