TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Ifẹ ni akoja ofin, eyi ti Wolii TB Joshua ni lọpọlọpọ- Olori Naomi Ogunwusi

Lẹyin o rẹyin, Wolii Temitope Balogun Joshua wọ kaa ilẹ lọ sinmi.

Opọlọpọ awọn eekan ilu lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ eto ikẹyin ti wọn se fun olori ijọ Synagogue SOAN naa.

Olori Naomi Silekunola to soju Ooni ti Ile Ife sapejuwe Wolii naa bi alaanu ti o nifẹ ara ilu pupọ.

TB Joshua

Oloye Aladun, Oloye Zaki ti Akoko ni ipinle Ondo ti Wolii TB Joshua ti wa naa ba BBC Yoruba sọrọ lorukọ awọn oloye to ku ti wọn jọ wa si Eko.

O sọrọ nipa ipa ribiribi ti Wolii TB Joshua ko ni Arigidi Akoko ati ohun to se laye awọn ara ilu Akoko.

TB Joshua

Bisoobu Tunde Adegbite to jẹ alaga ẹgbẹ ọmọleyin Jesu CAN ni ipinlẹ Eko naa sọrọ pupọ lori Wolii TB Joshua.

Bisoobu naa salaye pe TB Joshua pa ọpọlọpọ lerin nigba aye rẹ.

Koda, o salaye bi Wolii naa se bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ko to di nla bayii ni Eko.

TB Joshua

Aposle Abiodun Sanya Olu to ṣoju alaga Christian Association of Nigeria lapapo CAN Nigeria naa sọrọ nipa oloogbe TB Joshua.

Apostle ni sebi orukọ Jesu ni TB Joshua fi n se gbogbo nakn to n se laye ki ọlọjọ to de.

O ni nitootọ TB Joshua ko darapọ mọ ẹgbẹ ọmọleyin Kristi CAN sugbọn o n ṣiṣẹ iyanu loruko Jesu naa ni.

Apostle Abiodun ni adura lo ku ki awa ti a wa laye maa gba lori iṣẹ ọwọ wa ati nigba ti ọlọjọ ba de.