Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣiṣe- Bukola

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

Oluwafisayomi Amodemaja jẹ ọdọmọde oṣere to tun gbe fiimu ara rẹ jade gẹgẹ bii olootu ere.

Fiimu Abebi to kọkọ gbe jade jẹ eyi to sapejuwe pe o da lori iwa ipa ninu idile ati ipa to n ni lara awọn ọmọ nibẹ.

Abebi ni Iya oun, Bukola Amodemaja ni orisun iwuri oun.

Awọn miran to kopa ninu ere ọdọmọde yii ni Bimbo Oshin, Odunlade Adekola ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lọdun 2018 ni Fisayo Amodemaja bẹrẹ ere ṣisẹ.

Lati ara kikopa ninu ere ọmọde nile ijọsin ni Sọọsi lasiko ayajọ Children Day ni iya rẹ ni o ti bẹrẹ ere.

Abebi sọ afojunsun rẹ lọjọ iwaju ati pe ko di iwe kika oun lọwọ.

Bukola Amodemaja gba obi ati alagbatọ nimọran lati tubọ gbadura fun ọmọ wọn ki wọn si gbaruku ti wọn ninu talẹnti wọn.