Ibadan Gas tanker accident: Ọdọọdún la máa ń gbé igbá àgbo lọ́jà Bode àmọ́ àwọn kan kọ̀ lọ

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

"Bo ṣe agbado la ba le fọ́n, ka pe awọn aladua ki wọn ba wa ṣadua si gbogbo ọja Bode ki aburu ma ṣẹlẹ amọ ..."

Eyi lọrọ to jade lẹnu Iyaloja gbogbo ọja Bode nilu Ibadan nibi ti Tanka to ko afẹfẹ gaasi ti sirin to ya wọ inu ọja to si pa eeyan eeyan mẹrin tawọn mii farapa.

BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode lagbegbe Molete nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

"Ọdọọdun la maa n ṣe ọdun gbigbe igba agbo, a ti n ṣe nisisiyii, o le lọdun mejila, ẹmi to maa n gbe awọn ibeji si gbe wọn lọdun yii, wọn ba sọ pe ka ma na ọja o fun ọjọ meje o. Gbogbo wọn si ni wọn gbọ ṣugbọn ṣẹẹ mọ pe awọn kan o ni gbọ.

Alhaja Sikirat Makinde sọ fun BBC Yoruba pe amọ awọn taa gbọ́ ṣẹṣẹ boode ni o si yẹ ki gbogbo wa ṣe saaraa".

Awọn olutaja naa sọ iriri wọn pe gbogbo dukia awọn lo bajẹ ti kii sii ṣe nkan kekere rara.

"Awọn eeyan wa o ki n ta nkan lẹba ọna, ọkọ yẹn ya wa ba awọn eeyan ninu ọja ni to si pa wọn ti wọn n fa oku awọn eeyan jade labẹ ọkọ".

Ẹwẹ ajọ to n mojuto irina oju popo ni Ibadan ni awọn ṣa gbogbo ipa awọn atawọn oṣiṣẹ alaabo to ku to wa nibẹ lati bojuto iṣẹlẹ naa bibẹẹ kọ ko ba ju iroyin tawọn eeyan n gbọ lọ ki Tanka naa to gba ina.