Olusegun Obasanjo bu ẹnu àtẹ́ lu ìwé ìròyìn Nàìjíríà tó kọ̀ròyìn pé òun dá ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo ni oun ti gbọ nipa iroyin kan ti ko ni gbongbo ti wọn ni o jade ninu iwe iroyin Vanguard pe "Ẹgbẹ oṣelu tuntun de'lẹ ṣaaju ọdun 2023: Obasanjo yan gomina ana mẹta ni adari, o si pe ipade".
Oloye Obasanjo to wa ni ilu Kabul, Afghanista lọwọlọwọ gẹgẹ bi alejo aarẹ Ashraf Ghani fi ikede sita pe iroyin yii ti akọroyin kan to n jẹ Soni Daniel kọ, ofuutu fẹẹta irọ gbaa ni.
Ninu atẹjade ti Kehinde Akinyemi to jẹ olugbaninimọran pataki fun un lori ọrọ iroyin fi sita, o ni oun ko ṣe eto tabi gbero kankan lati da ẹgbẹ oṣelu kankan kankan silẹ lasiko yii tabi lọjọ iwaju.
Obasanjo ni iroyin irọ ti wọn po pọ yii jade si oun gẹgẹ bi iyalẹnu tori pe fun igba diẹ bayii ni oun ti woye gidi, akitiyan awọn kan lati ṣaa fa oun wọ inu agbo oṣelu.
Lori irọ tuntun ti wọn sọ yii ni Oloye Obasanjo wa ni "nibi ti emi tiwa o, ti ẹ ba ti ni o daarọ, oo gbud pada lọ sibẹ lọ ki wọn kaalẹ mọ".
Obasanjo ni ẹni to kọ iru iroyin bẹẹ ni lati ṣe ibẹwo si "Yaba Left" nibi ti wn ti n wo awọn to ni arun ọpọlọ ni ipinlẹ Eko. Bẹẹ naa lo na ẹnu eebu si ẹnikẹni to ba gbagbọ ninu iroyin naa.
"Mo ti jami lori ọrọ oṣelu ṣugbn pẹlu ipo mi ni Naijiria ati ni Afirika lai ba ṣekuṣẹyẹ, ati koda lagbaye, o yẹ ki ilẹkun wa ni ṣiṣi ni bẹẹ si ni o wa ni ṣiṣi fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ to ba fẹ wa gba imọran mi".
Oloye Obasanjo ni koda oun yoo da wọn lohun pẹlu gbogbo imọ ati oye ti oun ni lai tẹ sọdọ ẹgbẹ naa tabi ọlọdani.
"Bi ohunkohun ba ṣl, gbẹ oṣelu Oloye Obasanjo lasiko yii ni ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria to n koju iṣoro aisi aabo, awọn ti ebi ati iṣẹ n pa, ti ko riṣẹ atawọn to n koju oniruuru ipenija mii". O ni ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria to yẹ ko ri itusilẹ gba loun wa bayii.
O ni ki awọn to fẹ gba ọna ilẹkun ẹyin wọle lati mu Obasanjo ni tipatikuuku lati maa ṣe fefe ninu oṣelu bọwọ fun ipinu lati jẹ agba ilu alaiṣe oṣelu.
Ni tirẹ, o ni aarẹ tẹlẹri yoo tẹsiwaju ninu ipa rẹ gẹgẹ bii agba ilu to n gba ni nimọran, ti ni lẹyin, tabi pese iranwọ nigba to ba ṣeese ni Naijiria, ni Afirika ati ni gbogbo agbaye.

















