Ogun 2019: Ladi Adebutu ní ìdájọ́ iléẹjọ́ kò ní nǹkan se pẹ̀lú òun

Ladi Adebutu

Oríṣun àwòrán, PDP

Oludije fun ipo gomina ti ẹgbẹ oṣelu PDP n ti lẹyin fun ipo gomina nipinlẹ Ogun lasiko idibo apapọ ọdun 2019, Ladi Adebutu ti sọ pe, pẹlu-pẹlu idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ lọjọ Aje lori ọrọ oludije ipo gomina ipinlẹ naa, oun ṣi ni oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹnusọ fun ọgbẹni Adebutu, Afọlabi Ọrẹkọya ni, idajọ naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu boya Adebutu ni oludije tabi Kaṣhamu.

O ni ohun ti Adebutu gbe ka iwaju ile ẹjọ naa fun ayẹwo ni pipaṣẹ fun ajọ eleto idibo INEC lati gba orukọ rẹ gẹgẹ bii oludije ti ajọ naa damọ.

Àkọlé fídíò, 2019 elections: Ladi Adebutu ní òun ṣì ni olùdíje PDP fún ipò gómìnà l'Ogun

Orukọ Sẹnetọ Kaṣamu ni ajọ INEC gba wọle lẹyin idajọ ile ẹjọ giga kan to ni, ẹgbẹ PDP ko tẹle idajọ ile ẹjọ kan saaju ki o to lọ ṣe idibo abẹnu to gbe Ladi Adebutu wọle.

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa

Agbẹnusọ fun Ladi Adebutu naa ni, awọn ṣi n reti ki awọn adari apapọ ẹgbẹ oṣelu naa o gbe igbesẹ ti o tọ, gẹgẹ bi o ṣe ni ile ẹjọ naa paṣẹ ki wọn lọ ṣe.

Ninu ọrọ tirẹ, ikọ Sẹnetọ Kaṣamu ni awọn yoo yẹ ọna gbogbo to yẹ lati rii pe, ifẹ awọn ọmọ ẹgbẹ lo jọba ati pe alaafia wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa lai naani ẹni yoowu to ba dije fun ẹgbẹ oṣelu naa lẹyin o rẹyin.

Àkọlé fídíò, 2019 Elections: Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjíròrò Eko yóò bẹ̀rẹ̀

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun Sẹnetọ Kaṣamu, Austin Oniyokor, ba BBC News Yoruba sọ, alaafia ati igbega ẹgbẹ oṣelu PDP lo jẹ Sẹnetọ Kaṣamu logun.

O ni aṣofin agba naa ṣetan lati ba Ladi Adebutu tabi ẹnikẹni sowọpọ fun idagbasoke ẹgbẹ oṣelu PDP.