Wole Soyinka: Gbogbo àwọn tó ṣèjọba lẹ́yìn ìjọba ológun ló dá wàhálà tó wà nílẹ̀ yìí sílẹ̀

Aworan Soyinka,Kanu ati Igboho

"Àwọn tí yóò gbà ipò Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu tí wà nílẹ̀ báyìí".

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti sọrọ lori bi nkan ti ṣe n lọ lorileede Naijiria.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC, agbaọjẹ onimọ litiresọ yii ni nkan to bajẹ ni Naijiria ko ṣẹṣẹ bẹrẹ lori ijọba yii ṣugbọn ko yẹ ki wọn maa wa nkan ṣe sii.

O ni lati le r'ojutu si awọn ipenija to ba Naijiria, o di dandan ki awọn ọmọ ilẹ naa ṣe apero taa n pe ni Confab.

Soyinka ni eyi nikan ni ọna ti itẹsiwaju ati ijẹ orileede kan le fidi mulẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

Lasiko ifọrọwerọ yi, o tun mẹnu ba awọn họwuhọwu to n waye lori ipe fun ipinya Naijiria.

Ni paapa, o sọ ero ọkan rẹ nipa awọn ajafẹtọmọniyan to n pe fun iyapa Naijiria bii ti IPOB ti Nanamdi Kanu n dari rẹ ati ti awọn Ọmọ Oduduwa ti Sunday Igboho n dari.

''Igboho kan gbiyanju lati mu atunṣe ba nkan ti ijọba ti bajẹ ni. A ti ni awọn eeyan mii ti yoo gba ipo Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu bi wọn ba ko wọn nilẹ''.

O bẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe n fi agbara takuntakun mu awọn eeyan kan bi Nnamdi Kanu ti wọn lo n da alaafia ilu ru ṣugbọn ti wọn ko mura si awọn mii bi Miyetti Allah ati awọn agbebọn darandaran.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka

Soyinka sọ pe awọn darandaran jẹ ẹgbẹ to ni olori ṣugbọn ti ijọba ko gbe igbesẹ to yẹ lati mu awọn olori wọn.

O fi ẹdun ọkan rẹ han bakan naa pẹlu bi ijọba ko ṣe kara mọ aasiki ọrọ awọn ti awọn agbebọn lọ ṣeku pa ni Oke-Ogun.

O ni ọdaran pọnbele lawọn agbebọn wọnyi ti wọn si n fi ojojumọ pọ si.

Ni idahun si ibeere lori bi ijọba ṣe ni awọn n wa awọn to n ṣe onigbọwọ fun Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu o ni ko jẹ tuntun.

''Ṣebi nibi la wa ti wọn sọ fun wa pe awọn ti ri awọn to n ṣagbatẹru Boko Haram. Mi o ti ri ki nkankan tẹyin rẹ bọ abi iwọ ti gbọ nkankan ni?''

''Lọkan mi o, o yẹ ki ijọba apapọ tọrọ aforijin lọdọ Igboho ki wọn si ni ko maa lọ lalaafia''.

Lakotan, Soyinka rọ ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn ipenija to n koju Naijiria ki o si sọ ododo fawọn ọmọ Naijiria lori iṣejọba wọn.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'

''Ko si ẹni to n sọ pe gbogbo wahala yi bẹrẹ lasiko ijọba Buhari nitori gbogbo awọn to ṣe ijọba lẹyin ijọba ologun lo da si wahala to wa nilẹ yi.

''Lati igba ti a pada si ijọba alagbada ni awọn olori ti n ṣe aṣise nipa iwa to tako ijọba awarawa. Ninu awọn iwa yi ni bi wọn ṣe n diwọ mọ owo ijọba ibilẹ, ati inakuna owo ijọba.''