Yomi Alliyu SAN: Wo àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Yomi Alliyu, agbẹjọ́rò fún Sunday Igboho

Agbẹjọro Igboho ati Igboho

Oríṣun àwòrán, others

Yomi Alliyu jẹ agbẹjọro agba ni Naijiria, SAN. Ọdun 2017 lo di agbẹjọro agba.

Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ nipinlẹ Osun ni, ṣugbọn ilu Ibadan lo fi ṣe ibugbe to si ti n ṣe iṣẹ agbẹjọro.

Akọsilẹ nipa rẹ lori ayelujara Linkedin fihan pe oṣu Kẹwaa, ọdun 1986 lo ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi amofin ati agbẹjọro.

Ilu Ibadan ni ileeṣẹ agbẹjọro to da silẹ, Chief Yomi Alliyu & Co wa, nibi ti awọn agbẹjọro ati amofin ti n korajọ pọ ṣiṣẹ.

Fasiti ilu Eko,University of Lagos lo ti kawe gboye akọkọ laarin ọdun 1979 si 1980.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'

Lẹyin naa lo lọ si Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, laarin sdun 1980 si 1984.

Wọn gba sinu isẹ amofin ni Nasijiria lọdun 1985.

O lọ si ile ẹkọ girama Olivet Baptist High School, nilu Ọyọ. Yatọ si eyi, o tun lọ si ile ẹkọ girama Gbongan/Ode-Omu Anglican Grammar School, Gbongan nipinlẹ Osun.

Bakan naa lo kawe gboye ninu imọ Notary Public ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Yomi Alliyu lo wa lapa osi ninu aworan yi pelu Gomina ipinle Osun Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Facebook/Yomi Alliyu

O gba iwe ẹri nipa imọ Arbitration and Dispute Resolution ni Chartered Institute of Arbitrators

O gba iwe ẹri nipa ofin Civil Law ni fasiti Obafemi Awolowo, Ife.

Gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa ni ori ayelujara Linkedin, Yomi Alliyu ti fi igba kan jẹ ọmọ igbimọ oluṣakoso ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ipinlẹ Osun, OSBC, laarin ọdun 1995 si 1998.

Bakan naa lo wa lara ọmọ igbimọ to wadii bi awọn kan sẹ ta awọn irinṣẹ ti wọn n lo ni Asejire Dam ti owo rẹ to 200m nipinlẹ Osun laarin ọdun 1994 si 1995.

O tun di ipo pataki mu ni awọn ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Osun bi ileeṣẹ to wa fun ọrọ awọn ijọba ibilẹ; igbimọ to wa fun awọn oṣiṣẹ fẹhinti; igbimọ to n ṣeto yiya awọn oṣiṣẹ ijọba lowo fun ile kikọ (1995 si 1998).

Ẹwẹ, oun ni agbẹjọro to lewaju awọn agbẹjọro to ṣoju ijọba ipinlẹ Oyo nile ẹjọ giga lasiko ti Yinka Ayefele gbe ijọba lọ sile ẹjọ fun pe wọn wo ileeṣẹ rẹ, Music House, to wa ni opopona Challenge nilu Ibadan, lọdun 2018.

Yatọ si pe o jẹ agbẹjọro, iwadii fihan pe o tun jẹ oloṣelu.