Nnamdi Kanu: Àwọn àgbà Yorùbá ní ọ̀rọ̀ Sunday Igboho kò papọ̀ mọ́ ti olórí ikọ̀ IPOB

Yoruba ni iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.
Idi ree ti awọn eeyan kan nilẹ Yoruba fi n bẹru pe nibayi tijọba apapọ ti gbe Nnamdi Kanu, tii se asaaju ikọ ajijagbara IPOB, o seese ki wọn mu Sunday Igboho naa, to jẹ asaaju awọn eeyan to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation.
Amọ awọn eekan ọmọ ilẹ Yoruba kan ti n fesi lori ibẹru yii ati bi ijọba Naijriia se kede pe awọn ti ri Nnamdi Kanu mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Interpol ṣèrànwọ́ fún ìjọba àpapọ̀ láti mú Nnamdi Kanu
- Orí àgbá ẹ̀tù láwọn èèyàn Ibarapa jókòó lé, wàhálà ń bọ̀ - OPC mẹ́ta tó gba ìdáǹdè
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
Nnamdi Kanu ni olori ikọ ajijagbara to n pe fun idasilẹ orileeede awọn ẹya Igbo ti wọn pe ni Biafra.
Ọba Adetokunbo Tejuosho ni ọrọ Kanu ati Igboho yatọ sira:
Ninu awọn to ba BBC Yoruba sọrọ ni Ọba Adetokunbo Tejuosho tii se Olu ti Orile Kemta ati Basorun Seinde Arogbofa, to jẹ akọwe fun ẹgbẹ Afenifere.
Ninu ọrọ ti wọn sọ, awọn mejeeji ni bayi ti wọn mu Nanamdi Kanu, ohun to ku ni ko lọ siwaju adajọ lati wi tẹnu rẹ.
Oba Adetokunbo, nigba to n salaye afiwe ati iyatọ to wa laarin eto ipolongo ti Kanu n ṣe fun idasilẹ Biafra pẹlu ti Sunday Igboho to fẹ idasilẹ Oduduwa Nation, oriade naa ni ọrọ awọn mejeeji ko jọ ara wọn.
Ninu iwoye rẹ, Oba Adetokunbo sọ pe ohun gbogbo eeyan lo lẹtọ ifẹhonuhan labẹ ofin Naijiria, yala fun Biafra tabi Oduduwa Nation.
''Ijijagbara Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho ko papọ rara, iyatọ wa laarin Kanu ati Igboho.
Idi ni pe ko si ikọlu ni gbogbo ibi ti Igboho ti n ṣe iwọde amọ orisirisi lo ti ṣẹlẹ lọdọ awọn IPOB''
Oriade naa sọ pe awọn ko gbadura ki ogun ṣẹlẹ, bẹẹ si ni awọn ko faramọ ki eeyan maa pe fun ogun.
Bakan naa lo sọ pe wọn ko le mu Sunday Igboho lẹyin ti ọwọ tẹ Nnamdi Kanu bayi nitori wọn ko jọ ara wọn rara.
Amọ nkankan ti Oba Adetokunbo ni o yẹ ki ijọba ṣe ni ki wọn tẹ eti gbọ ikunsinu awọn araalu.
Sehinde Arogbofa ni atunto lo le fopin si ikunsinu araalu:
Ero ti Oba Adetokunbo naa si fara jọ ti Bashorun Sehinde Awogbofa pẹlu.
Awogbofa ninu alaye rẹẹ sọ pe o yẹ ki atunto waye ni Naijiria lati dẹkun aiṣedede to wa laarin awọn ẹya orilẹede yii.
''N ṣe lo yẹ ka forikori, ka fikunlukun, o si yẹ ki a ṣe atunto nkan nitori bi ohun gbogbo ti ṣe fi sapa kan lo n da wahala silẹ.''
''Bi awọn kan ti ṣe n ro wi pe ẹru ni awọn, ti awọn kan si ri ara wọn bii ọga, lo n da wahala silẹ pupọ.''
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Lakotan awọn mejeeji ni o yẹ ki ijọba gbiyanju lati ṣe atunṣe si eyi pẹlu bi araalu ṣe n ke irora.
Wọn ni ki ba maa si gbogbo wahala a fẹ ya sọtọ ti nkan ba lọ bo ti ṣe yẹ.




















