Biodun Okeowo: Kò sí ohun tó jọ eré ìfẹ́ láàrín èmi àti Dino Melaye

Dino melaye

Oríṣun àwòrán, officialomoborty/dinomelaye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣerebinrin lagbo tiata Yoruba, Biodun Okeowo, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Omo Borty, ti sọ pe ko si nnkan to jọ mọ ere ifẹ laarin oun ati sẹnetọ Dino Melaye.

Omo Borty lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fi soju opo Instagram rẹ.

Ninu atẹjade ọhun lo ti sọ pe oun gbọ nipa fọnran ohun kan to n tan kalẹ lori ayelujara ninu eyi ti wọn ti sọ pe oun ba Dino Melaye ṣere ifẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oṣere naa sọ pe oun ko ba ti moju kuro lara ahesọ naa ṣugbọn oun gbe igbesẹ lati sọrọ soke nitori igbeyawo oun ati ipo oun lawujọ gẹgẹ bii gbajumọ oṣere.

Biodun ṣalaye pe ọdun 2017 ni oun ṣalabapade sẹnetọ ọhun nibi ayẹyẹ igbeyawo kan, ti wọn si jọ ya aworan papọ gẹgẹ bii alejo ti wọn fiwe nibi ayẹyẹ ọhun.

Biodun Okeowo

Oríṣun àwòrán, officialomoborty

O ni "Lẹyin naa ni mo fi aworan yii soju opo Instagram mi, ṣugbọn mi o mọ pe aworan naa yoo di ohun ti awọn eeyan yoo maa gbe kiri gẹgẹ bii ahesọ pe mo n fẹ Dino."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ko ni nnkankan to jọ mọ ọrọ ifẹ pẹlu Dino nitori ọrọ itọju awọn ọmọ oun lo n mu ọmọ laya oun lọwọ yii.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Okeowo sọ pe "Ohun iyalẹnu lo jẹ fun mi nigba ti mo gbọ ti awọn eeyan sọ pe mo n fẹ Dino Melaye ati pe ni ṣe ni mo gba a mọ akẹgbẹ mi kan to jẹ oṣere tiata lọwọ."

"Lọwọ yii, ọrọ iṣẹ tiata ati owo ti mo n ṣe lo kan mi, ṣugbọn ti mi o ba fesi, yoo dabi pe lootọ ni mo n ṣe ohun ti awón eeyan n sọ nipa mi.

Mo ti sọ ṣaaju pe ko si nnkankan laarin emi ati Dino Melaye, inu mi yoo si dun ti awọn eeyan ba sinmi agbaja lori ọrọ yii."

Lẹyin naa lo ṣọ fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ pe oun ko ni ja wọn kulẹ, o si tun dupẹ lọwọ to kan si lati mọ okodoro ọrọ ọhun.