Baba Ijesha: Yomi Fabiyi rọ Iyabo Ojo láti gba àlááfíà láàyè

Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/realyomifabiyi/Instagram

Yoruba ni arẹmaja kankan ko si, amọ ajamarẹ ni ko sunwọn nitori ẹni to ba se ohun to dun mọ ni, le pada se ohun ti yoo dun ni.

Bẹẹ ni ọrọ ri bayii laarin awọn osere tiata meji to n tahun sira wọn lori ọrọ Baba Ijesha, eyiun Yomi Fabiyi ati Iyabo Ojo.

Bẹẹ ba gbegbe, Yomi Fabiyi lo n tako Iyabo Ojo lori awọn igbesẹ ti oserebinrin naa n gbe lori ẹsun asemase ti wsn fi kan Baba Ijesha, lati igba ti isẹlẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni ileẹjọ ti gba oniduro Baba Ijesha, eyi to tako awọn erongba Iyabo Ojo, ti ọpọ araalu si ti bẹrẹ si yọ suti ete si oserebinrin ọhun

Amọ Yomi Fabiyi ti wa fi ọrọ alaafia ransẹ si Iyabo Ojo pe ko jeburẹ lori ọrọ naa, ko si gba alaafia laaye.

Ọrọ ti Yomi Fabiyi kọ si Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

Fabiyi, ninu ọrọ tuntun to kọ soju opo Instagram rẹ kede pe oun ti dari jin Iyabo lai naani awọn kobakungbe ọrọ to ti sọ si oun saaju.

Oserekunrin naa ni bi ala ni awọn isẹlẹ to waye lori ọrọ Baba Ijesha naa n se oun, ti oun ko si lero pe oun ati Iyabo Ojo le taporogan sira awọn laelae.

"Eeyan daadaa ni Iyabo Ojo, ọrọ to sẹlẹ si n dun mi bii egbo ninu ọkan mi, n ko fẹ ba ọ ja tabi binu si ọ latinu ọkan mi wa.

Amọ bi ala ni gbogbo bi ọrọ yii se waye n jẹ si mi, jọọ dakun wa alaafia pẹlu ara rẹ ati awọn eeyan miran.

N ko si le sọ pe o kii se eeyan gidi mọ nitori awọn isẹlẹ to waye yii tabi ki n sẹ nipa iru eeyan to jẹ amọ mo ti forijin ọ nipa awọn ọrọ kabiti to sọ si mi."

Àkọlé fídíò, yyyy

Bakan naa ni Yomi Fabiyi tun gba Iyabo Ojo nimọran lati maa se daadaa siwaju, to si fikun pe oun lero pe awọn imọran naa yoo seso rere ninu rẹ.

Koda, ami ifẹ ni Yomi Fabiyi fi pari ọrọ rẹ si Iyabo Ojo naa.

Bẹẹ ba gbegbe, Iyabo Ojo ti kọkọ se fidio kan saaju pe oun ti dari jin gbogbo awọn eeyan to sẹ oun lori ọrọ Baba Ijesha.