Olusegun Agagu University: Àwọn ọmọ ìlú kọ́ ló ń fípa bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀, sùgbọ́n...

Kìí ṣe ọmọ ìlú ló ń fípa bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀, sùgbọ́n..

Ilé ẹ̀kọ́ fasiti Olusegun Agagu Science àti Technology Okitipupa ti ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún oṣẹ̀ méjì nítóri ètò ààbò tó mẹ́hẹ nilé ẹkọ́ náà.

Ilé Ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n tì pa lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà wọ́de ìfòhónúhàn nítorí òlè jíjà, ní àwọn ilé ìgbé ilé ẹ̀kọ́ náà, fifi ipá bá àwọn obìnrin lòpọ̀.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ ó kéré tán àwọn obìnrin mẹ́rin to jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni àwọn ọ̀daràn ti fi ipá bálópọ̀ ní yàrá wọn.

Ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà Damilola Okunomo sọ pé àwọn ọdaran náà ma n ji Fóònù, Laptop, àti àwọnn ǹkan iní wọn mííràn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́.

Ẹ̀wẹ̀, olùjábọ̀ fún BBC nílùú Okitipupa pé, ẹ̀rí mẹ́jì ní o wá lórí ọ̀rọ̀ náà, ó sàlàyè pé ọ̀rọ̀ àwọn ará ìlú àti àwọn akọ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ sí ara wọn gidi.

Bí awọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń sọ pé àwọn ọmọ ìlú ló n wọ ostẹli ká láti hùwà ibi náà ni àwọn ará ìlú ń sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sàlàyé pé, àwọn tó n gbé Igodan, Okunmo, Ayeka, Okitipupa àti Igbokoda ni wọ́n gbàgbọ́ pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi náà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣàlàyé pé àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ kan mú ẹnikan ti wọ́n fura sí pé olè ni ti wọ́n sì lùú pa nígbà tí kò sí ọlọ́paàá kankan láti gbàá sílẹ̀, wọ́n pé àwọn sọjà sùgbọ́n nígbà tí wọ́n yóò fi dé ẹ̀pa kò bóró mọ́, wọ́n ni ẹni náà ti kú.

Sùgbọ́n lálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn mííràn tún wá jalè gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, wọ́n fí ipá bá àwọn ọmọ náà lájọṣepọ, tí wọ̀n sí tún ṣe àwọn obìnrin náà báṣubàsu.

Èyí ló mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbà pé àwọn ará ìlú ló n ṣe irú iṣẹ́ náà tí wọ́n sì pe ìjọba láti wa ran àwọn lọ́wọ́, kí wọ́n gba àwọn sílẹ̀.

Sùgbọ́n ní ti àwọn ará ìlú pàápàá jùlọ Adeola Laguda sàlàyé fún BBC pé ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ náà kìí ṣe ọ̀rọ̀ ará ìlú, bí kò ṣé àwọn ọ̀daràn tí wan kàn ń da omí aláfíà ìlú rú.

O rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti má sọ pé àwọn ará ìlú ló n ṣe yìí, àti ará ìlú àtí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló le jẹ́ ọ̀daràn tó n ba ilú jẹ́, kìí ṣe àwọn kan pàtó.

Ọ̀gbẹ́ni Laguda wá ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ náà wá lágbára sí nígbà tí wan nlé olè méjì kan tí wan sì sálọ́ mó wọ́n lọ́wọ́ sùgbọ́n ọmọkùnrin kan tó n bọ̀ láti okó ní wọ́n mú pé olè ni, wọ́n sì lu ọkùnrin náà pa.

Ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni ilé ìwé náà Ni ọ̀pọ̀ àwọn ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí lóríṣiríṣi nínú ìlú náà lórí ọ̀rọ̀ ààbò, sùgbọ́n kò sí àbájádde kankan níbẹ̀.