Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

"Tẹ́ẹ bá kú sí àtìmọ́lé Ọlọ́pàá, wọ́n a kàn gbàgbé yín ni o, ẹ ṣáà máà ṣe ọkàn ọkùnrin, tí ikú yẹ́n bá dé, ẹ bẹ iku ko jọ̀ọ́ kó fún yín láyè láti sọ ti ẹnu yín".

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi ti sọ pe iṣẹlẹ ẹsun ti wọn fi kan akẹgbẹ rẹ, Baba Ijẹṣa ati bi ọrọ ẹjọ rẹ ṣe n lọ si fihan pe ọna orilẹede Naijiria ṣi jina lori ọrọ bibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.

Ninu idahun rẹ si awọn ibeere BBC Yoruba ninu ọgba ti igbẹjọ naa ti waye, Yọmi Fabiyi ni idi gan an niyi ti ọpọ awọn eeyan loke okun kii fẹ fi ni ohunkohun lati ṣe pọ pẹlu awọn smọ Naijiria lọpọ igba.

O ni ọpọlọpọ awọn to n pariwo le Baba Ijẹsa lori bayii ni wọn ko gbọ tẹnu rẹ ki wọn to maa kan an mọ agbelebu.

Gbajumọ oṣere tiata naa ṣalaye pe ohun to ku diẹ kaato ni fun awọn to fi ẹsun kan Baba Ijẹsa pe o n ba ọmọde sun lati wa dẹ okun fun pẹlu ọmọbinrin to ti balaga.

"Nigbati ọrọ yii kọkọ jade, ariwo ifipabanilopọ ni wọn kọkọ n pariwo ki wọn to bẹrẹ. O ya wọn tun ni o n ba ọmọde lopọ ni.

"Bi eeyan ba jẹ ẹni to fẹran ati maa ba ọmọde lo pọ ki lo de ti o wa jẹ pe ọmọbinrin to ti balaga lẹ wa fi ṣe idẹkun fun?"

Yọmi Fabiyi ni oniruru orukọ lawọn eeyan ti pe oun nitori pe oun n ja fun ẹtọ Baba Ijẹṣa. O ni ọpọlọpọ lo n pe oun ni agbodegba fun afipabanilopọ.

O ni egun n bọ lori gbogbo awọn to ba n lo ẹrọ ayelujara lati parọ mọ ọmọlakeji wọn.

"Ọ̀pọ̀ àwọn tó n ja yìí ò kàwé, bawo ni wọn ṣe le wa ja fun ẹtọ wọn?".

Yomi Fabiyi ni oun o le sọrọ fun awọn toku oun o ṣugbọn ni toun, ko ṣeeṣe ki oun tijuu pe oun mọ Baba Ijesha.

"Iṣẹ ti pọ ti a ti jọ ṣe, ti mo ba wa ni mi o mọ ọ ri, bi wọn ba lọ ko fiimu taa ti jọ ṣe jade nkọ".

O ni idi mii ni wipe nigba ti oun lọ bẹẹ wo toun ri i pe ko si ọpọ eeyan to ti wa bẹ ẹ wo, bo ba wa jẹ oun nikan naa ni oun ku pẹlu rẹ, ko buru.

Mi ò ní ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Baba Ijesha kò dára torí mi ò kí ń ṣe wèrè àmọ́ níbi tó báa dé yìí, mi ò lè ní mi ò mọ Baba Ijesha rí"

O fi kun un wipe "ko si bo ti wu ko ri, bẹẹ parọ mọ ọ ni, bẹẹ fi kun un ni o, gbogbo iya tẹẹ ba fẹ fi jẹ ẹ, ẹ o le kan an mọ igi, o ṣaa ma pada wa saarin wa. Ti ẹni to de la ri, a o mọ tẹni to mbọ".

Bo tilẹ jẹ pe Yomi ni oun kọ lẹta si ijọba ipinlẹ Eko lori ọrọ yii kan naa ati iya ti wọn ti fi jẹ Baba Ijesha kọja ofin, o ni ṣe ni oun tun gba ipe latọdọ Baba Ijesha pe oun wa ni ile iwosan lori aarẹ.

Bí wọ́n ṣe yí omiduro oṣiṣẹ ijọba onipele ikẹwaa si onipele ikẹrindinlogun mọ Baba Ijesha lọwọ ni ko jẹ ko tii ri eeyan kankan gẹgẹ bi Yomi ṣe sọ pe beeli yẹn to ba ti de ibi kan a fori ṣanpọn.

"Emi tilẹ ti n ṣiṣẹ lori onipele ikẹwaa ti inu mi ti dun, afi ti mo gba ipe Baba Ijesha pe o wa ni ileewosan".

Ni ti awọn mọlẹbi Baba Ijesha, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ, ko si ṣee fẹnu sọ tan bo ṣe wa ninu fidio yii ti aburo rẹ ti fariga niwaju kamẹra.