Ibadan train station: Ìrìrí àwọn aráàlúu Ibadan nínú ọkọ̀ Reluwé tuntun rèé
Lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ifilọọlẹ oju irin Reluwe Ibadan si Eko ati ipinlẹ Ogun, igbokegbodo ti gberasọ nibẹ ti awọn araalu si ti n lọ bọ.
Ijọba ipinlẹ Oyo ti ṣaaju sọ pe awọn ti n ṣeto lati sọ agbegbe naa, Moniya di gbagede karakata niluu Ibadan.
Kọmiṣọna fun iṣẹ ode ati eto irinna ni ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Dahud Kehinde Shangodoyin lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Awọn ero to bọlẹ ninu ọkọ yii ni inu awọn dun si nkan ti ijọba ṣe "torinaa o rọrun ju ka ko si ọkọ lati Ibadan si Eko lọ"
Ti ẹ ba de awọn orilẹ-ede nla nla kaakiri agbaye, e oo ri awọn gbagede karatakata to sun mọ ibudokọ oju irin, iru rẹ ni ijọba Seyi Makinde fẹ ṣe siluu Ibadan.
Fun apẹrẹ, ti eeyan ba de ibudokọ naa tan, yoo ri oniruru ọkọ ti yoo gbe lọ si ibikibi to ba n lọ, yala ọkọ aladani ni o tabi ti ijọba. Oniruuru ile itaja ati ounjẹ naa yoo suyọ.
Ẹwẹ, awọn araalu to ti bẹrẹ si ni wọ awọn ọkọ reluwee naa lọ ilu mii ba BBC Yoruba sọrọ lori iriri wọn yala o rọrun tabi owo rẹ gọbọi, tabi ko ṣee fiwe awọn ọkọ oju irin aye atijọ.