Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ṣí fìlà gba àdúrà ọjọ́ iwájú fún mi ni - Besco Azeez Tijani
"Ìjà láàrin Alhaji Sikiru Barrister àti Alhaji Kollington gaan ló jẹ́ kí àwa yìí dé òkè".
Alhaji Sikiru Ayinde Ayinde Agbajelola Balogun ti ọpọ eeyan mọ si Sikiru Ayinde Barrister ti gbogbo eeyan gba pe lai si ani ani, oun ni Baba baa ninu orin Fuji kikọ to si jẹ pe oun ni gbajugbaja olorin fuji ju nigba aye rẹ to si ni ọmọ pupọ to n tọpasẹ orin rẹ.
Lara wọn ni Alhaji Abdulazeez Besco Adisa. Ko kan tẹle orin Ayinde Barrister lasan, afi bii ẹpa lo ṣe jọ oloogbe Sikiru Ayinde Barrister.
Kii wa ṣe pẹlu oju lasan tabi iru ara kan naa ati bi wọn ṣe ga jọ ga deede, gẹlẹ bi ohun Alhaji Barrister ṣee ri naa ni Besco ṣe maa n kọrin.
Bẹẹ ba n gbọ orin Besco lai rii soju, ẹ o ro pe Barrister ni wọn n gbọ awo orin rẹ nibẹ, bẹẹ ba wa rii lati ọọkan tabi ki ẹ tilẹ sun mọ ọ, ẹ o ni Alhaji Barrister lo jinde.
Besco ba BBC Yoruba sọrọ nipa iṣẹ orin rẹ ati bi jijọ Barrister ṣe ti lana pupọ fun un.
Gbogbo ọna ti o n gba ṣe orin tirẹ lo jẹ wipe ati ara Barrister lo ti kọ ọ eyi si ti sọ oun funra rẹ di gbajugbaja ninu orin Fuji ti awọn eeyan n pe e kaakiri fun ayẹyẹ wọn bi wọn ba ti fẹ ni imọlara oloogbe Barrister.
Bo ṣe ya yin lẹ́nu naa lo ṣi BBC Yoruba lete silẹ nigba taa de oju agbo ti Alhaji Besco ti n kọrin ti ko si si iyatọ kankan laarin oun ati Barrister.