End SARS protest: Àwọn olùwọ́de EndSARS bíi mẹ́sàn án ló ṣì wà ní àhámọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́jọ - Ajàfẹ́tọ́

Kemisola Ogunniyi

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan ti ke si ijọba lati tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ lẹyin iwọde EndSARS to waye lọdun 2020.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ ko din ni eeyan mẹsan an to ṣi wa ni ahamọ ni ipinlẹ Ondo, Ekiti, Eko ati ilu Abuja.

Lara awọn eeyan naa ni Kemisola Ogunniyi to ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun jojolo ninu ọgba ẹwọn to wa lagbegbe Surulere niluu Ondo, iyẹn ni ipinlẹ Ondo.

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC lọdun 2019, Omoyele Sowore pin aworan Kemisola loju opo ayelujara rẹ, o ni ilu Akure ni wọn ti fi panpẹ ofin mu ọmọdebinrin naa nitori o farajọ ọkan lara awọn to dana sun ọọfisi ẹgbẹ APC to wa niluu naa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹjọro Kemisola, Tope Tomekun, o sọ pe awọn ti n gbe igbesẹ lati yọọ ninu igbekun to wa lati nnkan bii oṣu mẹsan sẹyin.

Kemisola Ogunniyi

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore

O ni "Lọwọlọwọ bi a ṣe n sọrọ yii, mo ti n kọwe ẹsun si gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolo, ati agbẹjọro agba, to fi mọ adajọ agba ipinlẹ Ondo lori ọrọ naa."

BBC Yoruba tun kan si ọkan lara awọn ajafẹtọ to n da si ọrọ ọhun, Netufo Tomide, o sọ pe kii ṣe iya kekere lo jẹ Kemisola ninu ahamọ to wa.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

O ni "Wọn mu Kemisola pẹlu awọn eeyan miran lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe awọn lo dana sun ọọfisi ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ifẹhonuhan EndSARS lọdun 2020."

O ṣalaye pe lara awọn to ṣi wa ni ahamọ ni ọmọ ọdun mọkanlelogun ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Ojo ati Ayodele Ibukun, eyii to ni oyun oṣu meji bajẹ mọ lara lasiko ti awọn ọmọ ogun n fiya jẹ, koda o ni wọn ko tii fọ inu rẹ ti oyun ọhun bajẹ si titi di asioko ti a n ko iroyin yi jọ.

Kemisola Ogunniyi

Oríṣun àwòrán, Kemisola Ogunniyi

O pari ọrọ rẹ pe gbogbo akitiyan awọn lati yọ Kemisola atawọn mii ni ahamọ ni ko tii so eso rere.

Lẹyin naa lo ke si ijọba lati fi oju ṣunukun wo ọrọ naa, ki alaiṣẹ ma baa jiya ẹṣẹ ti mọ ohunkohun nipa rẹ.

Oṣu kẹwaa ọdun 2020 ni iwọde EndSARS naa bẹrẹ ni irọwọrọsẹ, ṣugbọn nigba to di asiko kan, awọn janduku wọ aarin awọn oluwọde ọhun, ti wọn bẹrẹ si n da ilu ru.

Àkọlé fídíò, Àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko

Ọpọ ẹmi lo ba iṣẹlẹ naa lọ kaakiri Naijiria, to fi mọ awọn olufẹhonuhan atawọn agbofinro.

Bẹẹ naa ni ọpọ dukia sọnu, paapaa niluu Eko, Akure ati Benin.

Àkọlé fídíò, Awọn oluwọde ENDSARS ba BBC sọrọ