Ikeja gas fire: Dúkìá sòfò níbi ti iná ti ṣẹ́yọ lágbègbè Sheraton ní Ikeja l'Eko

Iroyin ti jade pe eeyan mẹta lo gbẹmi mi nibi iṣẹlẹ ibugbamu afẹfẹ gaasi to burẹkẹ lagbegbe Opic Plaza ni Ikeja, ipinlẹ Eko.
Ìjàmbá iná naa ṣẹ́yọ ní agbègbè Maryland Ikeja níwajú Sheraton àti gbọ̀gan ìtàjà Opic nílùú Eko.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójú tó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ṣe sọ nínú àtẹ̀jáde tí ọ̀gá àgbà àjọ náà fọwọ́ sí sàlàyé pé, ní kété tí àwọn òṣìṣẹ́ pánapaná de dé bẹ̀ ni wọ́n ri pé ọkọ̀ agbépo ló fa iná náà.
O ní ọkọ̀ náà tó gbé afẹ́fẹ́ gáàsì ni iná mú bi ó ṣe n yà wọ inú Ikeja.
Iná yìí ló ràn wọ àgbègbè ilé ìtàjà Opic ti ó sì tún ta bá àwọn ilé tó wà ni ẹ̀gbọ́ rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Maapu bi eeyan ṣe le rin de ibi iṣẹlẹ jamba ina yii niyii.

Gbogbo àwọn mọ́tò tí wọ́n gbé sílẹ̀ ní sí ibi tí wọ́n ń páàkì ọkọ sí.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Gbogbo àwọn onísẹ pàjáwìrì ló tí wà nílẹ̀ láti rí dájú pé gbogbo nǹkan bs sípò.
Gẹ́gẹ́ bi àwòrán àti fọ́nran ti LASEMA fi sọwọ́ sí ilé iṣẹ BBC o fi hàn pé àwọn ènìyàn farapa níbí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ọ̀pọ̀ dúkía sì sòfò.

Oríṣun àwòrán, LASEMA














