Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Páṣítọ̀ tó lu ìyàwó rẹ̀ pa, tó tún sin òkú rẹ̀ sílé wọn

Afurasi ti wọn lo lu iyawo rẹ pa

Oríṣun àwòrán, Akwa Ibom Police Command

Awọn ọdọ ìlú Ikot Ataku, nijọba ibilẹ Okon-Edet, nipinlẹ Akwa - Ibom kọlu ìjọ Omega World Global Ministry, lẹyin ti iroyin jade pe oludasilẹ ìjọ naa lo pa iyawo rẹ.

Ọwọ́ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom tẹ pasitọ naa, Ukachukwu Enoch Christopher, lẹyin ti wọn fi ẹsun kan pe o pa iyawo rẹ, to si tun sin oku rẹ sinu ọgbà ile ti wọn n gbe.

Ninu atẹjade to fi sita, agbenusọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Odiko Macdon sọ pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni ọwọ tẹ pasitọ, ẹni ọdun mọkandinlaadọta ọhun.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọsẹ kan ṣaaju ọjọ naa ni iṣẹlẹ naa waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọlọpaa sọ pe, èdè aiyede lo waye laarin afurasi naa ati iyawo rẹ, Arabinrin Patience Christopher, lẹyin to fi ẹsun kan obìnrin naa pe o n yan àlè, ati pe oun ni orísun ogun to n ja oun.

Ẹni ogoji ọdun ni Arabinrin Patience, to si bi ọmọ márùn-ún fun pasitọ naa.

Pasitọ naa jewọ pe fun awọn ọlọpaa pe oun lu obìnrin naa pa ni.

Alamojuto ile ti pasitọ naa n gbe, to tun ni sọọsi si, sọ fun BBC pe ọmọ rẹ ọkùnrin keji lo ke gbajare sita pe iya awọn ti di awati.

Nigba ti ẹni naa bẹrẹ iwadii lo ri iboji kekere naa ninu ọgbà ile naa.

Awọn ọlọpaa ti wu oku Patience jade, wọn si ti gbe lọ si mọsuari fun iwadii nkan to pa.