Iyabo Ojo and Omo'brish: Kí ló n fa ìjà láàrin ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ méjì?

Iyabo Ojo ati Iya rẹ

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣerebinrin, Iyabo Ojo sọ pe iya oun ni aisan Schizophrenia, to ni i ṣe pẹlu ilera ọpọlọ, ko to o ku ninu oṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Lasiko ti Iyabo ati ọrẹ timọ-timọ, Tosin Abiola, ti ọpọ mọ si Tocyn Omo Brish, n tahun si ara wọn lori ayelujara Instagram ni Iyabo tu asiri naa nipa iya rẹ.

Oṣerebinrin naa fi ẹsun kan Tosin pe o fọwọsowọpọ pẹlu oṣiṣẹ oun nigba kan, lati ba aye òun jẹ.

Iyabo ni "awọn eeyan kan ma n wa sinu igbesi aye rẹ lati fi ọ ṣe àtẹ̀gùn fun mimu iwa imọtara ẹni nikan wọn ṣẹ.

"Wọn a darapọ mọ ọ, wọn a mọ ìwọlé ati ijade rẹ, wọn a si lo ìṣòro rẹ lati fi ba ti ẹ jẹ, sugbọn o, emi kii ṣe ẹni ti wọn le ba ti ẹ jẹ."

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

O ṣalaye pe lootọ ni mama oun ni aisan ọpọlọ, "mo tọju rẹ daadaa, mo si nifẹ rẹ pupọ, sugbọn ọpọlọpọ ọdun ni ìwọ Tosin ma n fi ọgbọn pe mi ni àwọn orúkọ to tumọ si ẹni to ni aarun ọpọlọ.

Mo kilọ fun ọ lori rẹ, nitori mo ni igbagbọ pe o n fi ọgbọn fi iya mi ṣe yẹyẹ ni."

Iyabo Ojo sọ pe oun ti ṣetan lati ba ọrẹ òun, Tosin na ọrọ ija naa tan bi owó.

O fi ẹsun kan an pe, lati ọsẹ diẹ ni Tosin ti n sọ òkò eebu si oun, nitori pe oun ko faramọ ibasepọ rẹ pẹlu amugbalẹgbẹ oun nigba kan, Gbemi.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

"O le pe ara rẹ ni ọrẹ korikosun mi, ko ma a wa ba ọmọ isẹ ti mo mu bi ọmọ, àmọ́ to fẹ ẹ pa okoowo mi run ṣọrẹ.

Dandan kọ ni ọrẹ, to ba kọjú ija si mi, ma a kọju ìjà si ẹ."

Amin iyasọtọ kan

Iyabo Ojo bẹ̀rẹ̀ ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ pẹ̀lú máníjà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn olè jíjà

Aworan Iyabọ Ojo ati Manija rẹ tẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, The nation

Gbajumọ oṣere tiata, Iyabọ Ojo ti fẹsun ole jija kan ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ nigbakan ri, Gbeminiyi Adegbọla .

Adegbọla, gẹgẹ bi iroyin abẹle ṣe sọ, ni oludari ileeṣẹ Fepris Limited, ti Iyabọ Ojo da silẹ.

Lọjọru ni Adegbọla yii bọ soju opo ayelujara Instagram nibi to ti pariwo Iyabọ Ojo sita pe, o fi ẹsun kan oun pe oun lohun fẹ jẹ ileeṣẹ rẹ run.

Àkọlé fídíò, Ẹ pàdé olórin Fuji alhaji Besco tó jọ Ayinde Barrister to tún ń kọrin gẹ́lẹ́ bíi tirẹ̀

Adegbọla ni "O sọ pe mo ji ẹ lowo ko, emi ati iwọ naa mọ pe o ko ni kọbọ lọwọ nigba naa, a kan n ṣe ṣekarimi lasan ni.

Mo gbọ pe wọn ni o mu mi gẹgẹ bi ọmọ, ti mo si ba ileesẹ rẹ jẹ? Huumm, ọmọ kẹ, iya kẹ, ọmọ to maa n lu nita gbangba, to si maa n fi se ẹlẹya loju aye.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Se ọmọ ti o ko se nnkan daradara fun fun odidi ọdun mẹrinla ti gbogbo wa si mọ nipa bi okoowo yii se lọ, mo si fi gbogbo aye mi sin ọ.

O ni mo gbe owo rẹ, iwọ ati emi si mọ lasiko naa pe o ko ni kọbọ lapo, a kan n se Packaging ni, to si ti di awa kan lẹnu pe a ko gbọdọ tu asiri sita, koda, bi inu n bi wa. Ọlọrun yoo da laarin wa.

O ti le ni ọdun mẹta bayii ti ọrọ yii ti waye amọ o ko jẹ ko tan sibẹ, se nnkan mii wa nibẹ, ti o ko sọ ni?

Jọọ, fi mi silẹ jare, jẹ ki n gbe aye mi, ko si mu orukọ mi kuro ni ẹnu rẹ."

Iyabọ Ojo pẹlu bọ sori ayelujara Instagram tirẹ lati fesi si ọrọ Manija rẹ tẹlẹ naa lati fi ẹri ohun ti Adegbọla ji lọwọ rẹ han faye ri.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ninu ọrọ to kọ, Iyabọ Ojo ni Adegbọla n ko owo ileeṣẹ Fespris Limited lọ sinu aṣuwọn ara rẹ, lẹyin to n fun awọn onibara ileeṣẹ naa ni aṣuwọn ifowopamọsi rẹ, dipo ti ileeṣẹ naa.

Gẹgẹ bi Iyabọ Ojo ṣe sọ, manija rẹ tẹlẹ naa ko da owo naa pada sinu aṣuwọn ileeṣẹ.

O ni nitori iwa ole to ni Adegbọla n hu si ileeṣẹ oun, ni oun fi ti ẹka ileeṣẹ naa mejeeji to wa lagbegbe Ikẹja nilu Eko pa, ti oun si le awọn oṣiṣẹ ibẹ pẹlu ero pe awọn lo n ja oun lole.

O ni nigba ti oun ta gbogbo dukia oun lati fi bẹrẹ ẹka ileeṣẹ naa miran ni agbegbe Lekki Phase 1, ni Manija oun yii tun tẹsiwaju pẹlu jija ileeṣẹ oun lole, ti oun si n lero pe ẹni to ṣee fi ọkan tan ni.

Iyabọ Ojo ni oun jami lori ẹjọ naa tẹlẹ nitori pe iya oun ati iya manija oun naa bẹ oun pe ki oun fiye denu, ki oun si jami lori rẹ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé