Iyabo Ojo: Alábòsí àti olójúṣàájú ní àwọn akẹẹgbẹ́ mi lágbo tíátà

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Alabosi ni awọn osere tiata Yoruba, ẹ sọrọ lori Oniduro mi amọ ẹ dakẹ lori ẹni to ba ọmọde sun

Gbajumọ osere tiata, Iyabo Ojo, ko tii sinmi rara lori ọrọ Baba Ijesha ati ẹsun ti wọn fi kan pe o ba ọmọde se asemase.

Lọtẹ yii, awọn agbarijọpọ osere tiata ni Iyabo ta si lọtẹ yii, to si n fẹsun kan wọn pe alabosi paraku ni wọn.

Ninu fidio tuntun ti Iyabo Ojo gbe jade lori ọrọ Baba Ijesha loju opo Instagram rẹ, o ni oun gbọdọ sọ tinu oun fun wọn ni.

Iyabo ojo wa n bi awọn akẹẹgbẹ rẹ pe se wọn sun tẹlẹ ni, ni wọn ko se sọrọ nipa ẹsun asemase ti wọn fi kan ọkan ninu wọn, Baba Ijesha.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

"Eyi ti ko kan yin lẹ n da si, gbogbo yin lẹ n bu Tope Alabi pe o ni orin Oniduro Mi ko dara, se o sọ fun yin pe Alaseyori ni oun n ba wi ni.

To ba tiẹ wa jẹ pe oun lo n ba wi lootọ, ewo lo kan yin nibẹ, nitori eyi to kan yin, ẹ ko da si, ẹ mu ohun yin lọ, ẹ sọrọ.

Gbogbo yin lẹ n fi fidio orin sita bayii, amọ eyi to kan yin, ẹ gbe ẹnu dakẹ, ẹ ko beere ọmọ ti nnkan sẹlẹ si tabi Princess iya rẹ."

Iyabo Ojo tun n bi wọn leere pe melo ninu wọn gan lo ti pe Alaseyori lati wa kọrin fun oun bi tabi gbe orin rẹ sita.

O ni oun ko se atilẹyin fun ẹnikẹni ninu wọn, boya Tope ni abi Alaseyori funra rẹ nitori ko si ohun to kan oun nibẹ.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

O ni awọn osere tiata ko duro ti ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn se asemase pẹlu rẹ, nitori pe ara wọn lo se amọ se ni wọn n da si ọrọ awọn olorin ẹmi.

"Mo sọ fun yin nigba yẹn pe to ba jẹ ara ita lo se nnkan ti Baba Ijesha se, ẹ ti maa fi ẹhonu han, a ni ẹ kii se eeyan gidi ni agbo osere tiata wa.

Ootọ ọrọ ko ni ka ma sọ ohun, n ko si ni kẹ fẹran mi, gbogbo ẹyin tẹ dakẹ lori ọrọ Baba Ijesha, se o yẹ kẹ sọrọ lori orin Oniduro mi."

O ni sebi eeyan wọn ni Tope Alaseyori, gbogbo wọn se wa n dẹnu bo akọrin naa bayii, to si ni ki wọn sọ ara wọn gidi gan ni, ọrọ to le gidi, wọn ko sọ oju abẹ niko.

"Tẹ ba ti da si ohun ti ko kan yin, ojoojumọ ni emi Iyabo yoo maa jade lati sọrọ si yin. Alabosi ni yin, ẹ kii se eeyan to dara.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Kii kuku se pe mo korira Alaseyori nitori oun lo wa kọrin lasiko isin idagbere fun iya mi, mo si sun mọ daadaa.

Alaseyori, jọ mase da awọn osere tiata lohun, ti nnkan miran ba se ọ lọla, wọn yoo gbe ẹnu dakẹ ni."

O wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe ki awọn osere tiata naa mase maa da si awọn ọrọ ti ko ba kan wọn.