Baba Ijesha: Iyabo Ojo ní òun kò tíi jámi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ Princess, òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni

iyabo ojo

Oríṣun àwòrán, other

"Mo maa n roo tẹlẹ pe ijaba ni iṣoro orilẹede yii ti a n pe ni Naijiria ṣugbọn mo ti rii pe awa ara wa gan an ni iṣoro ara wa."

Ọrọ ti gbajumọ oṣere, Iyabọ Ojo fi bẹrẹ ninu fidio kan to n ja ranyinranyin lori ayelujara ree ninu eyi to ti n fi iha to kọ si beeli ti wọn fun Baba Ijẹṣa han.

Baba Ijesha ni eekan oṣere ti awọn ọlọpaa fi si ahamọ lori ẹsun iwa aṣemaṣe pẹlu majesin, tii se ọmọdebinrin adẹrinposonu nni, Princess.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun un ọdun 2021 ni adajọ Majisireeti agba kan ṣilẹkun anfani beeli silẹ fun Baba Ijẹṣa lori ọrọ ailera ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Akungba Suicide: Ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ọ̀gá iléẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí irú èèyàn tí Feranmi Fasunle jẹ́

Iyabọ Ojo ni o fihan gbangba pe ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria ni iwa imọtaraẹnikan ni ironu wọn. Eyi lo si faa ti ọpọ maa fi n de ijọba ti iwa kiko ọrọ ilu si ikawọ arawọn.

O ni oun ko ti jami lori ọrọ ọmọdebinrin ti wọn fẹsun kan baba Ijẹṣa pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu.

O fi kun pe bi ọpọ ba ri ohun to ṣẹlẹ si ọmọdebinrin naa gẹgẹ bi eyi ti ko kan wọn