PDP governor's meeting: Wo àbájáde ìpàdé àwon Gómínà PDP ní Ibadan

Gomina Makinde, Tambuwal ati Duoye Diri, Ortom, Fintiri n joko takurọsọ nile iba ipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Ohun ti awọn gomina ẹgbẹ oṣelu PDP sọ ree nibi ipade ti wọn ṣe nilu Ibadan.

Apapọ awọn gomina to jẹ ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party, PDP ti tọka awọn nnkan marun ọtọọtọ ti yoo mu opin de ba awọn iṣoro to n koju orilẹede Naijira lọwọlọwọ.

L'ọjọ Aje ni mejila ọtọọtọ ninu awọn gomina mẹẹdogun to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo pejupesẹ si gbọngan nla igbalejo IITA to n bẹ ni opopona Mọniya nilu Ibadan lati ṣe apero lori ọrọ aje ati eto aabo orilẹede Naijiria tofimọ awọn ọrọ to niṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu naa.

Lẹyin ipade bonkẹlẹ to waye fun bi i wakati meji, awọn gomina naa fi ohun kan ṣe agbekalẹ abajade ipadae naa:

1. Ipade naa kesi aarẹ orilẹede Naijria lati fi aba ṣọwọ si ile igbimọ aṣofin lati lẹ ṣe atunṣe ofin orilẹede yii ki agbara le to awọn ijọba ipinlẹ lọwọ lori eto aabo nipa ṣiṣe agbekalẹ ọlọpaa agbegbe ati eto aabo mii.

Àkọlé fídíò, Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

2. Wọn parowa si aarẹ lati pe ipade igbimọ ọlọpaa orilẹede Naijira ni kiakia, ninu eleyii ti Aarẹ, awọn Gomina ati awọn alẹnulọrọ mii wa lati jiroro lori awọn ọna abayọ si awọn iṣoro to n koju iṣọkan Naijira, paapaa julọ ọrọ ọlọpaa.

Awọn gomina naa fun ohun ṣọkan pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣe pataki ni didaabo bo ijọba awa arawa, nitori idi eyii lo si fi yẹ ki rira nnkan elo, idanilẹkọ ati itọju awọn oṣiṣẹ ajọ naa di nnkan ti ijọba mu lọkunkundun.

3. Bakan naa ni ipade naa gbe lẹyin igbesẹ apapọ awọn Gomina orilẹede Naijiria, awọn Gomina agbegbe Ariwa ati Gusu wi pe ṣiṣẹ idasilẹ ọgba ti maalu ti le maa jẹ oko ni ọna abayọ si wahala awọn agbẹ ati darandaran, pẹlu alaye wi pe Naijiria nilo atunto ki agbara ati ojuṣe le pọ si i lọwọ awọn ijọba ipinlẹ.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

4. Ipade naa parọwa si gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati ṣiṣẹ pọ ninu iṣọkan ati alafia lai si ẹlẹyamẹya, gẹgẹ bi ipade naa ṣe n kesi ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn bẹnu atẹ lu gẹgẹ bi ẹgbẹ ti ko kan oju oṣuwọn lati gbe igbesẹ akin ki alafia le jọba lorilẹede yii, ki wọn si kọ ibi ara si agbekalẹ akanṣẹ ati ilana ti yoo ṣe anfani fun iṣọkan orilẹede yii.

5. Ipade naa tun mẹnuba ipe fun ile igbimọ aṣofin lati gbe igbẹsẹ lati lori ofin eto idibo ti yoo ki eto idibo maa lọ ni irọwọrọsẹ lorilẹede yii

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Awọn to pejupesẹ sibi ipejọpọ naa ni: Gomina Aminu Waziri Tambuwal ti ipinlẹ Sokoto, Gomina Udom Emmanuel ipinlẹ Akwa Ibom, Gomina Douye Diri ti ipinlẹ Bayelsa,

Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, Gomina Dr. Ifeanyi Okowa ti ipinlẹ Delta, Gomina Ifeanyi Ugwuanyi ti ipinlẹ Enugu,

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Gomina Nyesom Wike, ti ipinlẹ Rivers, Gomina Oluseyi Abiodun Makinde ti ipinlẹ Oyo,

Gomina Ahmadu Umaru Fintiri ti ipinlẹ Adamawa,

Gomina Godwin Obaseki ti ipinlẹ Edo, Gomina Bala Mohammed ti ipinlẹ Bauchi ati Mahdi Mohdigbakeji Gomina ipinlẹ.

PDP governor's meeting: Àwọn gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ẹgbẹ́ nílùú Ibadan

Kini o ti kókó sele?

Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ìpàdé nílùú Ibadan

Ipade awọn gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ ni gbọngban nla igbalejo IITA to n bẹ lopopona Moniya nilu Ibadan.

Mejila ninu awọn gomina mẹẹdogun to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti darapọ mọ ipade naa. Iroyin sọ wi pe awọn kan ṣi n bọ lọna.

Ipadae naa da lori ọrọ aje ati eto aabo orilẹede yii tofimọ awọn ọrọ to niṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu PDP.

PDP governor's meeting: Àwọn gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ẹgbẹ́ nílùú Ibadan

Lara awọn gomina ti o ti wa nikalẹ ni Dr. Okezie Ikpeazu, gomina ipinlẹ Abia, Hon. Ahmadu Umaru Fintiri ti ipinlẹ Adamawa, Udom Emmanuel

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

ti ipinlẹ Akwa Ibom, Bala Muhammed ti ipinlẹ Bauchi, Duoye Diri ti ipinlẹ Bayelsa, Dr. Samuel Ortom lati ipinlẹ Benue, Benedict Ayade ti ipinlẹ

Cross River, Dr. Ifeanyi Okowa ti ipinlẹ Delta, Dr. Ifeanyi Ugwuanyi ti ipinlẹ Enugu, Godwin Obaseki ti ipinlẹ Edo, Nyesom Wike ti ipinlẹ

PDP governor's meeting: Àwọn gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ẹgbẹ́ nílùú Ibadan

Rivers,Aminu Waziri Tambuwal ti ipinlẹ Sokoto, Darius Ishaku ti ipinlẹ Taraba, Bello Matawalle ti ipinlẹ Zamfara State ati Gomina Ṣeyi Makin ipinlẹ Ọyọ ti o jẹ olugbalejo nibi ipade naa.

Gomina Aminu Waziri Tambuwal ti ipinlẹ Sokoto to jẹ alaga awọn gomina gomina ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣide ipade naa ki wọn to kesi oniroyin lati yẹba fun wọn nibi ipade ni nnkan bi i iṣẹju diẹ si aago meji ọsan.

Ilé iṣẹ BBC wà níkàlẹ̀ láti jábọ̀ àbájáde ìpàdé náà.

Amin iyasọtọ kan

Awọn gomina ẹgbẹ PDP bẹrẹ ipade nilu Ibadan

Gomina Makinde, Tambuwal ati Duoye Diri n joko takurọsọ nibi apejẹ ipade awọn gomina PDP

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn gomina ipinlẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP n dari ni Naijiria ti n gunlẹ si ilu Ibadan fun ipade kan, eyi ti wọn pe laarin ara wọn labẹ aburada ẹgbẹ awọn gomina lẹgbẹ oṣelu PDP.

Ipade awọn gomina PDP yii lo n tẹle eyi to ti kọkọ waye saaju losu Kẹrin ọdun 2021 nipinlẹ Benue, ti akori ipade naa si tun da lori ipo ti Naijiria wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni afojusun wọn fun ipade naa, gẹgẹ bi wọn se fi sita, ni ọna ti ẹgbẹ oselu PDP fẹ gba lati jẹ ọna abayọ fawọn ọmọ Naijiria yatọ si ẹgbẹ oselu APC.

Gomina Makinde, Tambuwal ati Duoye Diri, Ortom, Fintiri n joko takurọsọ nile iba ipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Ireti wa pe awọn gomina mẹẹdogun ti wọn dibo yan labẹ ẹgbẹ oselu PDP ni Naijiria ni yoo peju sibi ipade naa.

Lara ohun ti wọn yoo jiroro le lori nibi ipade naa, gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ṣe sọ, ni awọn ọrọ to ṣe koko nipa orilẹede Naijiria lapapọ, bii gulegule ọrọ abo to n mẹhẹ ati ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Gomina Makinde, Tambuwal n joko takurọsọ nile iba ipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Lara awọn gomina to ti gunlẹ silu Ibadan fun ipade naa ni Gomina Tambuwal ti Sokoto, Samuel Ortom ti Benue, Duoye diri ti Bayelsa, Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu, Ahmadu Umaru Fintiri ti Adamawa.

Bẹẹ ba si gbagbe, nibi ipade akọkọ to waye nilu Markudi naa, ni wọn ti beere fun eto atunto Naijiria ati mimu adinku ba agbara ijọba apapọ.

Gomina Makinde ki gomina Ortom kaabọ sile ijọba nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Awọn ilana yii ni wọn ri bii ọna abayọ lati gba Naijiria lọwọ ogun abẹle miran nitori ọpọ laasigbo to n ba Naijiria finra.

Gomina Makinde, Tambuwal ati Duoye Diri n joko takurọsọ nile iba ipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde