Lizzy Anjorin: Kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kí obìnrin gba ọmọ tọ́ tàbí kó san owó fún ẹni tí yóò ba gbé oyún

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba to tun jẹ oniṣowo, Lizzy Anjorin to bi ọmọ tuntun laipẹ yii ti tun salaye ohun ti oju rẹ ri lasiko to diwọ disẹ sinu fun igba akọkọ.
Osere tiata naa, ẹni to salaye ọrọ yii lati fi yin Ọlọrun Ọba fun oore nla to se lori aye rẹ, tun sọ ipa ti iya rẹ ko lasiko to bimọ akọkọ naa.
Lizzy ṣalaye loju opo Instagram rẹ pe ẹni ọdun mẹtalelogun ni oun wa nigba ti oun bi ọmọ oun akọkọ, ki oun to bi omiran le lọsẹ meji sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Màá pe Kọ̀mísánà ọlọ́pàá Eko àti igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Amofin
- Shehu Sani fi olùwọ́de Yoruba Nation ṣe ẹlẹ́yà torí òjò tó tú wọn ká
- Àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji, Amoo Igisekele, jáde láyé
- Àwọn olùwọ̀de Yoruba Nation mú afurasí òṣìṣẹ́ DSS níbi ìwọ́de l‘Osogbo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
O ni "Mo bi akọbi ọmọ mi nigba ti mo wa ẹni ọdun mẹtalelogun, oun ti oju mi ri lọdun naa lọhun ko ṣe e fẹnu sọ."
Lizzy ṣalaye pe o ṣoro fun iya oun lati le gbọ bukata oun ati ọmọ lasiko naa, ṣugbọn iya naa gbiyanju lati ba oun tọju ọmọ naa, bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki oun ma lee lọ sile ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin
Nigba to n sọrọ nipa ojuse iya si awọn ọmọ, o ni ẹṣẹ ni ki eeyan bi ọmọ nigba ti ko ni owo lati tọju irufẹ ọmọ bẹẹ, eredi ree ti oun fi n ṣiṣẹ takuntakun ki oun to bi ọmọ miran.
O ni "O ṣoro fun iya mi lati ran mi lọ sile ẹkọ, ṣugbọn awọn kan ni ọmọ mẹwaa, wọn ri owo lati tọ wọn, nigba ti awọn miran ni ọmọ kan ṣoṣo ti wọn ko si le tọju wọn."
"Ironu yii lo mu ki n pinnu lati tẹ ipa mọ iṣẹ ọwọ mi."
Ohun ti oju Lizzy Anjorin ri ki oyun to de
Oṣere naa sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe oun ko kundun ibalopọ lọ titi, oun maa n lo awọn ogun kan to maa n dena oyun, ṣugbọn ọjọ igbeyawo oun gan ni oyun duro lara oun.
Lizzy ni "Mi o lero pe mo le loyun rara nitori mo n lo awọn oogun kan, nigba ti mo ṣe igbeyawo, n ṣe lo da bi pe mo n ṣe ere ori itage ni."

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram
Kii se ẹsẹ pe ki obinrin miran ba ni gbe oyun
Nigba to n sọrọ lori ilera obinrin, Lizzy sọ pe eeyan ko le fi ilera obinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn we iyawo ile to ti pe aadọta ọdun, nitori naa ni oun ṣe gbero pe ki oun fun obinrin miran lowo lati gbe oyun ọhun.
Ẹwẹ, nigba to n sọrọ lori ọmọ rẹ to ṣẹṣẹ bi ninu fidio kan to ṣe loju opo Instagram rẹ, Lizzy ni kii ṣe ẹṣẹ ki eeyan sanwo fun ẹni ti yoo ba gbe oyun ọmọ rẹ.
O ni "Ẹyin obinrin, ti ẹ ba fẹ bi ọmọ, ti ẹ si ti le ni ogoji ọdun, ẹ kọkọ ro ti ilera ara yin, ti ẹ ba sanwo fun ẹni ti yoo gbe oyun ọmọ yin ki ṣe ẹṣẹ, bẹẹ si ni kii ṣe ẹṣẹ ti ẹ ba gba ọmọ tọ, ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni tan yin jẹ o."

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram
Bo tilẹ jẹ pe o ni kii ṣe pe oun ti n ṣẹ oyun tipẹ lo jẹ ko to akoko diẹ ki oun to bi ọmọ naa, gẹgẹ bii ahesọ ọrọ ti awọn kan n sọ lori ayelujara, o ni ilera lo ju, o si yẹ ki eeyan maa wo ti ilera ara rẹ ko to sọ pe oun fẹ bi ọmọ.
- Èèyàn márùn ún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ẹ̀ni ọdún 42 kan l'Ẹ́dẹ
- 'Ẹ wòó kò jọọ́, èmi kò lè so nọ́mbà fóònù mi mọ́ NIN tíjọba Nàìjíríà ń gbé kiri'
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- ICPC ń wá ọkọ ọmọ Buhari àtàwọn méjì míì lórí ṣíṣe $65,000,000 kúmọ kùmọ
- Àwọn eèyàn kan fara gbọta níbi ìjà àwọn Aṣọ́bodè àti Ònífàyàwọ́ nígboro Iseyin lọ́jọ́ ọdún
Gbajumọ oṣere naa pari ọrọ rẹ pẹlu ifẹmi imoore han si ọkọ rẹ ati dokita to n tọju rẹ lasiko to wa ninu oyun.
Lẹyin naa lo gbadura fun awọn ololufẹ rẹ ti ko tii bi ọmọ pe, ọlẹ ayọ yoo sọ ninu wọn laipẹ.
















