Sunday Igboho: Wo bí àwọn ọmọ Yorùbá ṣe tako ìhàlẹ̀ láti dá ìbò 2023 dúró

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram

Ọrọ to ba kọju si ẹnikan, Yoruba ni a maa kọ ẹyin si ẹlomiran bii ilu gangan.

Eyi lo mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba kan maa tako ọrọ ti Sunday Igboho sọ pe, awọn ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba ko ni jẹ ki idibo waye lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Kaarọ oojire lọdun 2023.

Idi ree ti awọn ọmọ Yoruba kan se n fesi si ọrọ naa, ti wọn si n kọju oro si idunkooko si eto idibo gbogbo gboo to ti ẹnu Sunday Igboho jade.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, alagba Abdulhakeem Adegoke Alawuje sọ pe Igboho lẹtọ lati sọ nkan to wu lọkan ṣugbọn ko lagbara lati paṣẹ fun ijọba.

Alawujẹ to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ Yoruba Welfare Group fi kun pe, bi Yoruba ko ba dibo, ọna ati dero ẹyin lorilẹede Naijiria ni wọn ba bọ yẹn.

Ami idanimọ ẹgbẹ́ YWG

Oríṣun àwòrán, YWG

''Bi ọwọ ẹni ko ba ti tẹ eku ida, a kii beere iku to pa baba ẹni. A ti n pe gbogbo awọn baba wa nilẹ Yoruba ki wọn kesi awọn to n kọrin ọtẹ pe ki wọn tọwọ ọmọ wọn baṣọ.''

O tun sọ pe awọn arijẹ nidi mọdaru lo n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ati pe, ko si Ọba Alade nilẹ Yoruba kankan to n gbe lẹyin wọn.

Ọmọde laa fi ṣoogun ogboju ṣugbọn o yẹ ki o fi laakaye ṣe - Niyi Akintola

Ninu ọrọ rẹ agbẹjọro Adeniyi Akintola to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko to si tun jẹ ilumọọka oloṣelu, o ni oun ko faramọ ọrọ ti Igboho sọ.

Niyi Akintola ni lootọ ni ofin faye silẹ fun ẹnikẹni lati sọ ero ọkan rẹ gẹgẹ bi Igboho ti ṣe sọ, ṣugbọn ohun gbogbo lo ni aala tiẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe Sunday Igboho ko fi laakaye kun eto ijijagbara to n se nitori ọgbọn ju agbara lọ.

''Iru Igboho yẹ ko wa lawujọ, kii sii ṣe gbogbo nkan to ba sọ la le ko danu, ti kii ba ṣe nitori nkan to ṣe awọn ajinigbe, ko ba gbogo ju bayii lọ''

Aworan Akintola

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Akintola/Facebook

Amọ o ni Igboho ko gbẹnusọ fun apapọ awọn Yoruba, bakan naa lo ni oun ko faramọ pe ki idibo ma waye lawọn ipinlẹ kaarọ o jiire lọdun 2023.

''Mi o faramọ pe ki o maa si ibo. O si nibẹ, o n beere pe bawo ni wọn ti ṣe pin?''

Nibi iwọde fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti Sunday Igboho ati awọn ọmọ Yoruba mii dijọ ṣe ni Osogbo, lo ti sọrọ nipa idibo ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

Igboho sọ fawọn to wa nibẹ pe awọn Gomina ipinlẹ ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria nifẹ si ki Yoruba wa ni ominira ṣugbọn ẹru n ba wọn nitori owo oṣooṣu ti wọn n gba lọdọ ijọba apapọ.

O ni yatọ si awọn Gomina, awọn lọbalọba naa wa lẹyin awọn to n pe fun fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Titi di ba ṣe n sọrọ yi, ko ti si Gomina kankantabi Ọba alade Yoruba to jade lati sọ pe awọn wa lyin ipe iyasọtọ Naijiria.