Muhammadu Sanusi II: Mi ò ni ìpinu láti du ipò òṣèlú kankan ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Emir ilu Kano tẹlẹ, to tun jẹ Alfa Agba ìjọ ẹlẹ́sìn Tijaniyya ni Naijiria, Muhammadu Sanusi, ti sọ pe oun ko ni erongba lati du ipo oṣelu ni Naijiria, àmọ́ o ni oun yoo tẹsiwaju lati ma a tọ araalu sọna lori oludije to yẹ.
Muhammadu Sanusi II, to sọ ọrọ naa nibi ipade akọkọ to ṣe pẹlu àwọn Muqaddimai ati Shaykhs ninu ìjọ ẹlẹ́sìn naa gẹgẹ bi Caliph wọn sọ pe awọn nkan ti oun n sọ ko tumọ si pe oun yoo ṣe oṣelu.
O ni "ti a ba ri awọn to ṣe e fi inu tan, to ba sọ pe awọn yoo ṣe dáadáa fun araalu, a gbọdọ parapọ̀ ṣe atilẹyin fun wọn".
- Wo ikú tó pa Kenneth Kaunda, Ajìjàgbara fún òmìnira Áfíríkà tó gbẹ̀yìn
- Nkan n bẹ! Páṣítọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ pa torí pé ó ń yan àlè
- Sunday Igboho ní agbébọn tí kò bá kúrò nínú igbó Yorùbá láti ọjọ́ Aje rugi oyin
- N5M ni a pàdánù lásìkò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lé wa kùró ní Sabo - Àwọn oníbárà
- Dúkìá sòfò níbi ti iná ti ṣẹ́yọ lágbègbè Sheraton ní Ikeja l'Eko - LASEMA
O ni ti araalu ko ba ṣe bẹ ẹ, o se e ṣe ko lewu fun Naijiria
O ni eto ẹ̀kọ́ fun awọn ọmọde ṣe pataki, ki awọn ìṣòro to n koju Naijiria to dopin.
O sọ pe laisi ẹ̀kọ́, ẹrú ni awọn ọmọ ẹ̀yà Ariwa Naijiria yoo maa ṣe fun awọn ẹ̀yà to kù.
Sugbọn, àwọn ẹnikan lara awọn alfa mii to tun sọrọ níbi eto naa, Sheikh Halliru Maraya, sọ pe yatọ si awọn imọran Sanusi, o ṣe pataki lati fi adura kun.
O sọ pe o jẹ dandan fún àwọn eeyan lati ni ibẹru Ọlọ́run, ki àwọn adari naa si daabo bo ẹ̀mí ati dukia awọn eniyan, ki wọn o si pese fun aini wọn.















