K1 De Ultimate: Bí Barrymade bá ní alágbàfọ̀ bàbá òun ni mí, oríire ni mo ṣe

Àkọlé fídíò, 'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

Alhaji Wasiu Ayinde ti gbogbo ènìyàn mọ̀ si K1 de Ultimate tẹnu bọ ọrọ lori ọrọ ti Barrymaade, ọmọ abúrò Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister sọ si i wi pe oun (Kwam1) ni alagbafọ baba òun, Sikiru Ayinde Barrister.

K1 pa itan pe baba Barrymade gangan ni Nuru ti o jẹ aburo si Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ti awọn si jẹ ọ̀rẹ́ tímọ́ tímọ́.

O ni "Ọmọ tó bá lanu gbàgà sọ̀rọ̀ sí àgbà", bí ẹni fọwọ osi juwe ile baba rẹ ni nitori naa, "baba ati iya rẹ lo n ba wi".

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ lè nífẹ sí

Alhaji Wasiu Ayinde ni bi oun ba tilẹ wa jẹ alagbafọ fun Alhaji Sikiru Ayinde Barrister, oriire lo jẹ fun oun tori oun sin in tọkan tọkan.