Sikiru Ayinde Barrister: Kwam 1 ní Agbajelola ló ṣe olùlànà fún àwọn olórin Fuji òde òní

Oríṣun àwòrán, Fuji Opera
Gbajugbaja olorin Fuji ati Mayegun ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde, ti ọpọ eeyan mọ si K1, ti kan sara si ẹni to da orin fuji silẹ, Sikiru Ayinde Barrister.
Wasiu lo gboṣuba kare naa fun Barrister nibi ayẹyẹ iranti ọdun kẹwaa to jade laye, eyii to waye ni Ikoyi, ni ipinlẹ Eko.
Nibi ayẹyẹ naa ti ọpọ ẹbi, ọrẹ ati ojulumọ Barrister peju si ni Kwam 1 ti sọ pe orin fuji ni Barrister duro fun ni igba aye rẹ.
- Báyìí ni Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ṣe wọ ṣọ́ọ̀ṣì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bá bàbá rẹ̀ ṣe ìdúpẹ́ ìwúyè
- Ọmọ Risikat olójú búlúù méjèéjì jẹ̀bùn oríire àti ìfà ńlá
- Ta ni obìnrin tó fẹ́ bá Dino Melaye ṣe ìgbéyàwó lọ́jọ́ kejì Kérésì?
- Ọdún Kérésì di kọ̀ọ̀ l‘Eko, ìjọba dènà Kánífà òpin ọdún, ayẹyẹ ṣíṣe àti òde fàájì
- Ẹ́ tú èékánná lọ́rùn Sowore, ẹ kò ní ẹ̀rí láti ba ṣẹjọ́ - Ẹgbẹ́ Amòfin Amẹ́ríkà
O ni "oni yii ni a n ṣiṣọ loju eegun ohun ti Barrister fi gbogbo aye rẹ ṣe, to si tun jiya le lori fun gbogbo agbaye lati mọ pe orin Fuji ti wa orisun rẹ̀ ri."

Oríṣun àwòrán, Fuji Opera
Kwam 1 ṣalaye pe "a le fi orin Fuji we orin Reggae laye atijọ, ṣugbọn lode oni, orin Fuji gangan ni ohun ti wọn mọ wa fun kaakiri agbaye."
Wasiu sọ pe Barrister lo ṣe olulana fun awọn olorin Fuji bi oun, ati pe Barrister ko ku, nitori ohun to ti ṣe silẹ ṣi n fọhun sibẹ.
Lẹyin naa lo ki awọn ẹbi Barrister ku oriire pe wọn gbẹyin ologbe ọhun, paapaa lori ipa to fi silẹ ko to fi aye silẹ.

Oríṣun àwòrán, fuji opera
Ọjọ kẹsan an, oṣu Keji, ọdun 1948 ni wọn bi Sikiru Ayinde Barrister si idile Salawu Balogun ni ilu Ibadan.
Barrister gbe awọn orin to le ni aadọrin jade, bẹẹ naa lo tun gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ ko to dagbere faye lọdun 2010.
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- Ẹ má bínú pé mo kọ́kọ́ ní akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá péré ni wọn kó nílé ìwé Kankara - Garba Shehu
- Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù
- Ilé aṣòfin àgbà yọ gómìnà nípò, ẹni tó fi owó ìlú rán ọmọ lọ sí Amẹ́ríkà
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin













