Penis Captivus: Àlàyé rèé lórí bí olólùfẹ́ méjì tó lẹ̀pọ̀ ṣe rí ọ̀nà àbáyọ

Awọn ọlọpaa gbe obinrin abilekọ to se asemase naa

Oríṣun àwòrán, Pai Robins Ogweng Akiiki/Facebook

Kii se igba akọkọ ree ti iroyin yoo maa jade lorilẹede Naijiria nipa ọkunrin ati obinrin to lẹ pọ lasiko ti wọn n se ere ifẹ.

Ọ̀pọ eeyan miran ko gbagbọ pe iru isẹlẹ yii le waye, ti wọn si maa n ro pe ejo lọwọ ninu, ati pe isẹ aye ni.

Lọtẹ yii, ọkunrin kan ni orilẹede Uganda, Pai Robins Ogweng Akiiki ti ke gbajare loju opo Facebook rẹ lọjọru nipa isẹlẹ kan to waye.

Àkọlé fídíò, Ẹ pàdé olórin Fuji alhaji Besco tó jọ Ayinde Barrister to tún ń kọrin gẹ́lẹ́ bíi tirẹ̀

Gẹgẹ bi ọkunrin naa se wi, se ni ọrọ ọhun da bi ere itage nigba ti ọkunrin kan ha si oju ara obinrin abilekọ kan lasiko ti wọn n sere ifẹ.

Ilu kan ti wọn pe ni Gulu, to wa lẹkun ariwa orilẹede Uganda, ni isẹlẹ naa ti waye.

Bi isẹlẹobinrin abilekọ to se asemase se waye

Oríṣun àwòrán, Pai Robins Ogweng Akiiki/Facebook

Gẹgẹ bi ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ, Robins Ogweng Akiiki ti wi, lẹyin ti awọn ololufẹ mejeeji yii ba ara wọn lopọ tan, lo nira fun ọkunrin lati yọ kuro luju ara obinrin naa.

O ni gbogbo igbiyanju awọn mejeeji yii lati pinya lo ja si pabo, idi si ree ti wọn se figbe bọnu ke si ara adugbo pe ki wọn wa gba awọn.

Amọ Robins salaye pe lẹyin o rẹyin ọkọ obinrin naa gbọ nipa isẹlẹ yii, to si wa si ibi ti nnkan ọkunrin miran ti ha sinu oju ara iyawo rẹ.

Ọkọ obinrin yii si lo de, to fi ọwọ si ibadi awọn mejeeji, ti awọn mejeeji si pinya, ti nnkan ọkunrin naa si yọ loju ara obinrin naa.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

Lọwọ lọwọ bayii, awọn mejeeji ti wa ni agọ ọlọpaa, gẹgẹ bi ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ ti wi.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha