Phyically Challenged: Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà

Phyically Challenged: Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà

Aṣoju ajọ kan to n risi igbayegbadun awọn akanda ẹda, Abiọsẹ Oluwafunkẹ Falade ti ṣe alaye ọrọ wi pe gbogbo nnkan ti awọn abarapa n ṣe ni awọn akanda ẹda naa le ṣe ti wọn ba ri iranlọwọ ti o peye gba.

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ nibi apero ọlọdọọdun awọn akanda ẹda to waye nilu Ibadan l'ọjọ Ẹti, Falade ni awọn akanda ki i ṣe eeyan to yẹ ki a maa wo gẹgẹ bi ẹni ti ko le ri aye gbe lai tọrọ bara.

O ni gbogbo nnkan ti awọn abarapa n ṣe naa ni awọn to ni ipenija ara le ṣẹ ti wọn ba ri iranlọwọ gba lọwọ ijọba.

O tẹsiwaju wi pe ko si bi eeyan ṣe le jẹ akanda ẹda to ti ko ni si nnkan kan ti o le lo lati ṣiṣẹ ti yoo si maa gbọ bukata ara rẹ lai ṣe agbe jẹun.

Phyically Challenged: Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà

Falada fi kun ọrọ rẹ pe akanda ẹda ti ko ba sọ ireti nu le ṣe aṣeyọri ju ẹni ti o jẹ abarapa lọ.

O ni, "A wa si ibi lati wa kọ awọn ọmọ ti wọn jẹ akanda wi pe ile aye wọn ọwọ wọn lo wa, nitori pe ko si ẹnikan kan to n bọ lati wa gba wọn la. Awọn nikan lo le gba ara wọn la".

Phyically Challenged: Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà

O ni lara ipenija ti awọn akanda ẹda n koju ni pe awọn eeyan ki i fẹ sunmọ wọn lawujọ bi ẹni pe alaisan ni wọn de ibi wi pe wọn ki i fẹ gba wọn si iṣẹ pẹlu ibẹru wi pe akanda ẹda ko le ṣiṣẹ bi o ṣe tọ.

Falade tẹsiwaju pe ijọba ni ojuṣẹ ti o pọ lati ṣe ki aye le rọrun fun awọn akanda ẹda.

O pe fun ipẹsẹ ọna ti awọn akanda ẹda to wa lori kẹkẹ le maa rin ati aye ti wọn le maa duro si ni awọn ile itaja ati ibi ẹro ti a ti n gba owo.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn iranlọwọ yii ba wa fun awọn akanda ẹda, ki a maa ṣe agbe ki a to jẹun yoo dinku laarin wọn.

Ọ parọwa si awọn akanda ẹda pe ki wọn ma sọ ireti nu, ki wọn si ma jẹ ki ipenija ara ti wọn ni sọ wọn di alagbe.

Phyically Challenged: Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà