Ekiti Monarch Kidnapping: Àwọn agbébọn gbé orí adé míì lọ l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Starland
Awọn agbebọn kan ti ji Ọba Benjamin Oso, to jẹ ori ade ilu Eda Ile, ni ijọba ibilẹ Ila Oorun ipinlẹ Ekiti gbe lọ.
Iroyin sọ pe wọn ji ọba Eleda ọhun gbe lasiko to n bọ lati ọna oko rẹ, ṣugbọn wọn fi iyawo rẹ silẹ.
Iṣẹlẹ yii ti mu ki Eleda di ori ade kẹta ti awọn ajinigbe yoo na ọwọ gan laarin oṣu mẹta sira wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ ìlú kọ́ ló ń fípa bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀, sùgbọ́n...
- Ìwọ́de 'Yoruba Nation' foríṣánpọ́n ní ìlú Offa, ẹ wo ohun tó fàá
- Kìí ṣe iṣẹ́ bárà nìkan ni àwọn àkàndá lè ṣe jẹun, àìsí ìrànlọ́wọ́ ní kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe fújà
- Olofa Ina tọrọ àforíjìn lọ̀wọ̀ àwọn òṣèré tíátà obìrin lórí ọ̀rọ̀ tó sọ níbi ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- "A ń sàárò ọgbọ́n ìṣèjọba àti òṣèlú tí Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi ni nígbà ayé rẹ̀"
- Àwọn agbébọn pa ìyàwò èèkàn olóṣèlú ní Ibadan, ọlọ́pàá ní adigunjalè ní wọ́n
Ọga agba fun ikọ Amotekun nipinlẹ Ekiti, ọgagun Joe Komolafe lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.
O ni gbogbo ẹṣọ alaabo ni ipinlẹ Ekiti to fi mọ awọn ọlọpaa, awọn ọmọ ogun, ikọ Amotekun atawọn ọdẹ ilu ti kan lugbẹ bayii lọna ati ṣawari ọba ọhun.
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Sunday Abutu sọ pe awọn ṣi n fi oju ṣunukun wo iṣẹlẹ ọhun, awọn yoo si sọrọ nipa rẹ ti akoko ba to.
Abutu sọ pe ileeṣẹ awọn ti ṣetan lati fọ ipinlẹ Ekiti mọ lọwọ gbogbo awọn kọlọransi ati ajinigbe pawo.
Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria jabo pe oju iyawo ọba naa ni awọn ajinigbe naa ṣe gbe lọ lọna oko wọn niluu Eda Ile.
Ẹnikan to sun mọ ẹbi naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe erongba awọn ajinigbe naa ni lati gbe tọkọ-taya naa lọ, ṣugbọn wọn jọwọ olori rẹ leyin ti ori ade ọhun bẹ wọn.
Ẹni naa sọ pe "Ọba ati olori ni awọn ajinigbe naa dena de."
"Awọn mejeji ni wọn ko ba ji gbe lọ, ṣugbọn wọn jọwọ olori lẹyin ti ọba bẹ wọn, wọn si gba lati gbe oun nikan lọ."



















