Baba Ijesha: Princess ní ojoojúmọ́ ni Ijesha ń tọ̀rọ̀ ìdáríjìn lọ́wọ́ òun ní àgọ́ ọlọ́pàá

Arabinrin Damilola Adekoya, tii se adẹrinposonu, ti ọpọ eeyan mọ si Princess, ti ke si gbogbo araalu pe ẹnikẹni ti Baba Ijesha ba ni ajọsepọ aitọ pẹlu ọmọ rẹ, wa fi to oun leti.
Princess, lasiko to n salaye bi gbajumọ osere naa se yaju si ọmọ rẹ nidi ajọsepọ laitọ, wa kesi awọn obi tabi alagbatọ to ba mọ pe Baba Ijesha ti ni ibalopọ aitọ pẹlu ọmọ oun ri tabi ti aburo rẹ, ko wa sọ fun oun.
Princess, ẹni to salaye pe oun fi inu wenu, oun wa jẹ iwọ, tun gba awọn obi nimọran lati mase jẹri ẹnikẹni lati da ọmọ wọn da.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi si lẹ́yìn ikú rẹ̀ ju ojú ayé rẹ̀ lọ - Florence Ajimobi
- Nǹkán yan, wọ́n ń ṣe ìkówójọ fún Olorì Damilola láti fi gba ilé l‘Eko
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Wo oore tí Ramadan n ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tó n gbà á
- Ìdí tí mo fi bú sẹ́kún nílé aṣòfin àgbà rèé - Smart Adeyemi
Bakan naa lo tun gba awọn obi to ba ni ẹsun lori Baba Ijesha niyanju lati lọ̀ si agọ ọlọpaa to wa ni Panti, ki wọn lọ fi ẹjọ sun nitori ibẹ ni baba Ijesha wa.
Princess tun sisọ loju rẹ fun araye pe ojoojumọ ni oun n yọju si agọ ọlọpaa Panti nilu Eko, nibi ti wọn ti Baba Ijesha mọ, ti ọkunrin naa si maa n rawọ ẹbẹ si oun pe ki oun jọọ, dari jin oun.
O ni awọn ọlọ̀paa si n se iwadi rẹ lọwọ, to si ti jẹwọ pe ko si irọ ninu ẹsun ti wọn fi kan.
"Baba Ijesha ni oun ko hu iru iwa yii ri fun ọmọde kanakan ayafi ọmọ mi, amọ bawo ni mo se fẹ mọ pe otitọ lo n sọ.
Se iru ohun to yẹ ki Baba Ijesha fi san oore ti mo se fun ree, haa, eeyan ma le o."

Alaye ree lori bi Baba Ijesha se ba ọmọ mi loopọ - Princess

Alaye ti n jẹyọ lori ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ ti wọn fi kan gbajumọ osere tiata Yoruba kan, Olanrewaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha.
Obinrin kan to jẹ gbajugbaja adẹrinposonu to jẹ alagbatọ ọmọdebinrin ti wọn fi ẹsun kan Baba Ijesha ba lopọ, ti wa soju opo ayelujara Instagram rẹ, lati sọ fun araye nipa bi isẹlẹ naa se waye.
Adẹrinposonu naa to n jẹ Princess Comedian lo n fi omije nla sọ bi isẹlẹ naa se ba a lọkan jẹ to ati bo se waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà TAMPAN sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀ṣùn bíbá ọmọdé lòpọ̀ tí wọn fi kan Baba Ijesha
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Àkàrà tú sépo! Wo bí ọ̀rẹ́ Olorì Damilola ṣe gba Alaafin mọ lọ́wọ́
Obinrin naa, ẹni to koro oju si bi awọn eeyan kan se n da lẹbi, tun salaye pe kii se gbogbo igba ni Baba Ijesha n wa ba ọmọ naa lopọ fun odidi ọdun meje.
O ni ẹẹkan pere lo wa sile oun ni ọdun meje sẹyin, to si se ọmọ naa bi ọsẹ ti n soju.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Princess ni lati igba ti isẹlẹ naa ti waye ni ọdun meje sẹyin, ni ara ti n fu oun pe nnkan ti yatọ lara ọmọ naa, to si ti n kuna gidi nipa ẹkọ rẹ.
O ni ọpọ ẹbi lo n da oun lẹbi pe oun ni atẹnumọ ju amọ oun mọ pe nnkan ti yipada lara ọmọ naa.
Obinrin adẹrinposonu naa ni awọn obi to wa ladugbo oun lo gba ki awọn ọmọ wọn wa maa gbe ni ọdọ oun, ti wọn si fi awọn ọmọ naa se oun laanu.
O fikun pe mẹfa ni awọn ọmọ ti oun gba tọ, ọkunrin mẹta ati obinrin mẹta.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye?
Princess ni Baba Ijesha lo wa ba oun pe oun ni isoro nipa ẹkọ rẹ, o ni oun n fẹ iranlọwọ lati wọ ileẹkọ fasiti, ti oun si fi si lẹsinni.
Obinrin naa tun salaye pe nigba keji ti baba Ijesha wa lẹyin ọdun meje wa se pẹki akoko ti anti oun wa wo oun, ti oun si fẹ sin jade nigba ti onitọun n lọ sile.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O ni oun sọkalẹ lati lọ si geeti fun, ti oun ko si lo ju isẹju mẹta si mẹrin lọ nisalẹ, amọ oun ko mọ pe nnkan ti sẹlẹ.
"Baba Ijesha tun pada wa ni ọjọ keji lati mọ boya ọmọ naa ti sọ ohun to sẹlẹ fun gbogbo ile. Ọmọ naa ni Ijesha sọ pe ki oun kalọ sidi mọto oun lati wa gbe eso ti oun ra wọle.
Amọ nigba ti wọn de isalẹ lo tun ba ọmọ naa se isekuse lẹẹkeji, lati igba naa ni ko ti wa sile mi mọ amọ nigba to ba nilo iranlọwọ, o maa n pe mi.
- Kò sí orílẹ̀èdè tí kìí la àkókò ìnira kọjá - Bola Tinubu
- Wo oore tí Ramadan n ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tó n gbà á
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Ta ló ń fi orúkọ Oluwo lu àwọn obìnrin ní jìbìtì lórí ayélujára?
- Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fún ẹyà Igbo ní ilẹ̀ Biafra àti òmìnira tó ń fẹ́ - Ẹgbẹ́ 52 lókè ọya rọ United Nations
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- El-Rufai yarí kanlẹ̀, ó ní ìjọba òun kò ní san owó fún àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé
Lọjọ kan ni mo sọ fun pe ki lo de to se n sa fun mi, o nilo iranlọwọ, o si joko sile, se emi ni ki n wa ko owo fun ọ ninu ile ni.
"Ni ọsẹ keji ti isẹlẹ naa waye, ni awọn alasẹ ileẹkọ ọmọ naa pe mi pe ki n yọju sawọn pe ọmọ naa n joko sori ọkunrin to jẹ ẹgbọn rẹ, to si n rin idi mọ ni itan.
Onigbagbọ gidi ni awọn obi ọmọ naa, ti wọn si ro pe ogun ẹmi lo n ja ọmọ ọdun meje naa, koda n ki gba ki wọn wo iwokuwo lori tẹlifisan."
Princess ni ijakulẹ ti ọmọ naa tun n ni ninu ẹkọ rẹ, ko jẹ ki ara oun balẹ nitori wọn fi ọmọ naa rẹ oun lẹkun ni.
O ni ọrẹ oun lo ba ọmọ naa sọrọ lati mọ idi ti isesi rẹ se yipada lẹyin ọdun meje ti isẹlẹ naa waye, ti ọmọ naa si jẹwọ oun to wa laarin rẹ ati baba Ijesha, ti otutu si mu oun.
Idi ree ti mo se ni ki baba Ijesha yọju si mi, ti emi ati mama mi si ti mura silẹ pe a maa bi nipa ọrọ naa, ko sọ otitọ.
"A wa seto ẹrọ ayaworan CCTV, ta si ni ki gbogbo eeyan to wa ninu ile jade lọ. Nigba to de, o ri awọn to wa se CCTV naa, mo sọ fun pe awọn osisẹ DSTV ni wọn, mo fẹ sin wọn jade.
Ni kete ta jade lo bẹrẹ si ni wa inu ile kiri lati ri pe ko si eeyan kankan ninu ile tabi pe a fi kamẹra sinu ile.
Ẹ ri bi eeyan se buru to. N ko tiẹ le maa salaye awọn nnkan to se nitori a n wo bo se n se lori foonu wa.
O wa mu ọmọ naa lọ sile idana nitori pe o mọ pe ko le si ẹrọ ayaworan nibẹ."
Idajọ ododo yoo waye, ẹ ba a dẹru ba mi ju bẹẹ lọ
Obinrin naa wa koro oju si awọn eeyan to n sọ oun ti wọn ko mọ lori ọrọ yii lati sọra nipa isẹlẹ naa.
Princess ni to ba wu awọn eeyan, ki wọn halẹ mọ oun, ohun to daju ni pe idajọ ododo yoo waye lori ẹsun toun fi kan baba Ijesha.
"To ba wu yin, ẹ lọ dena de mi, idajọ yoo waye. Se nitori pe Baba Ijẹsha jẹ osere tiata Yoruba lẹ se n gbe lẹyin rẹ?
Ko si ọmọde to yẹ ki ẹnikẹni fi tipa ba lopọ, ko dara rara.





















