Biafra: Ẹgbẹ́ 52 lókè ọya ní ààbò tó mẹ́hẹ ń kọ olórí pípé ọmọ Nàíjíríà lóminú

Agbarijọpọ ẹgbẹ oke oya mejilelaadọta kan, CNG ti rawọ ẹbẹ si ijọba Naijiria ati ajọ iṣọkan agbaye, lori bi idasilẹ orilẹede Biafra yoo ṣe d'ohun fun awọn ẹya Igbo.
Ẹgbẹ CNG tun na ika alebu si ẹgbẹ ajijagbara idasilẹ orilẹede Biafra, IPOB pe o ti n sọ ara rẹ di ẹgbẹ alakatakiti to n da wahala silẹ, to si tun n doju ogun koju Naijiria, eleyi to ni ko dara to.
Amọ ẹgbẹ naa tun tọka si ileri ati ọrọ aarẹ Mohammadu Buhari gẹgẹ bi ileri ori ahọn ati ihalẹ lasanlasan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ta ló ń fi orúkọ Oluwo lu àwọn obìnrin ní jìbìtì lórí ayélujára?
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- El-Rufai yarí kanlẹ̀, ó ní ìjọba òun kò ní san owó fún àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé
- Omi àlàáfíà Nàíjíríà kò le tòrò àyàfi... - Afenifere
- Ó tún n rúgbó bọ̀! Ṣé lóòótọ́ ni Olori Damilọla ti sá kúrò ní ààfin Ọyọ?
- Ajínigbé jí èèyàn lọ́nà Ife sí Ikire, ọdẹ ìbílẹ̀ àti ọlọ́pàá wọnú igbó láti wá wọn rí - ọlọ́pàá Osun
CNG ni ko din ni ọtalelẹẹdẹgbẹrun ati mẹwaa, 970 awọn akẹẹkọ ti awọn ajinigbepawo ti ji gbe lapa oke ọya laarin oṣu kejila ọdun 2020 si oṣu kẹrin ọdun 2021.
Wọn ni ọpọlọpọ awọn akẹkọọ yii lo ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe yii, ti wọn si ti pa ọpọ ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ CNG naa Abdulazeez Suleiman, ninu atẹjade kan ni ko si igba kan ri ninu itan Naijiria to jẹ pe awọn janduku, ọdaran ati ajinigbe lo gba iṣakoso apa oke ọya bi ti ijọba Buhari yii.
O ni awọn ajọ agbaye gbogbo tun ni lati dìde si bi eto abo lorilẹede Naijiria ṣe ti wa dojuru bayii, bi ẹsẹ telọ.
O fi kun pe paapaajulọ awọn orilẹede bi ilẹ Gẹẹsi ni lati dide, gegebi ajọṣepọ rẹ pẹlu Naijiria, lati rii daju pe ijọba n se ojuse to yẹ lori idaabobo awọn eeyan orilẹede Naijiria.
O ni ki awọn orilẹede agbaye mase gbagbe pe bi nnkan ba daru lorilẹede Naijiria, yoo da omi alaafia Afirika naa ru pẹlu.















