IPOB UK Asylum: Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí ọmọ ẹgbẹ́ IPOB àti MASSOB ṣe lè jàǹfàní ṣíṣe àtìpó ní Britain

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wo nkan to yẹ ni mimọ bi ọmọ ẹgbẹ IPOB baa fẹ jẹ anfaani atipo ilẹ Gẹẹsi.
Ikede ilẹ Gẹẹsi pe awọn yo bẹrẹ si ni maa gba awọn atipo ọmọ ẹgbẹ ajijagbara Indigenous People of Biafra (IPOB) ati ti Movement for the Actualization of the Sovereign State of Biafra (Massob) ti n mu iriwisi wa ni Naijiria.
Bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ti se n kan sara si ilẹ Gẹẹsi lori igbesẹ yi lawọn mii paapa ijọba Naijiria ko foju ree wo.
- Chelsea, Arsenal, Liverpool, Tottenham Man City, Man United yọ ara wọn kúrò nínú ìdíje Super League tuntun
- Èéti jẹ́ tí Iyabọ Ojo fún ọmọ rẹ̀, Priscilla ní gbèdéke ọjọ́ orí 24 láti ṣe ìgbéyàwó?
- Wo ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU Ile Ife fi gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Àwọn agbébọn tún ti jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní fásitì kan ní Kaduna
Ninu ilana tuntun ti wọn gbe kalẹ yi, o ni awọn amuyẹ kọọkan ti ẹni to ba jẹ anfaani isatipo yi gbọdọ se.
Pataki julọ nibẹ ni pe o gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB tabi Massob to n koju idẹyẹsi.
Awọn ilana mii ree to gbọdọ tẹle boo baa fẹ jẹ anfaani ilana atipo to si silẹ yi:
1.Iwadii finifini ẹni to fẹ satipo gbọdọ waye:
Ilẹ Gẹẹsi sọ pe awọn yoo se iwadii lati mọ boya lootọ ni ẹni to n wa atipo yi jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB lootọ.
Lara iwadii yi ni pe wọn yoo sayẹwo boya o ti kọwe fun iwe igbelu saaju.
Lori iwe yi, wọn yoo wo boya ẹni to n wa atipo yi ti gba iwe igbelu visa ki wọn to se ifọrọwanilẹnuwo fun lati di atipo.
Lara ayẹwo naa ni pe wọn yoo se idanwo boya o le sọ tabi kọ ninu ede Gẹẹsi.
- Ó dá wa lójú pé Eyitayo Jegede á borí nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn- Ondo PDP
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Olufon, Ọba Adekunle Magbagbeola tó wàjà
- Tani Mahamat Kaka Idriss Deby tó di aàrẹ̀ tuntun ilẹ̀ Chad lẹ́yìn ìṣekúpani bàbá rẹ̀?
- Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ìdálẹ́bi fún Derek Chauvin lórí ẹ̀sùn gbogbo lórí ikú Floyd
2. Ọtọọtọ ni wọn yoo yẹ atipo kọọkan wo:
Awọn alasẹ ilẹ Gẹẹsi yoo se iwadii lati mọ boya idi pataki wa kawọn to le gba eeyan naa wọlẹ wọn fun isatipo.
Wọn o ni ko awọn eeyan jọ labẹ isọri abule tabi ilu fun anfaani atipo.
Eeyan kọọkan ni wọn yoo sagbeyẹwo boya o tọ si ki wọn gbaalaaye fun isatipo.
Bi orileede ẹni naa ko ba buwọlu iwe adehun idaabo bo awọn atipo, ko ni le jẹ anfaani yi.
3. O gbọdọ ni idi pataki to fi fẹ se atipo:
Ninu awọn amuyẹ yi ni pe ẹni naa ko gbọdọ ni adisọkan ẹgbẹ oselu kankan to n tẹle.
Koko ibeere kan ni pe ẹni ti o n wa atipo njẹ nitori adisọkan oselu to ni ni wọn fi n dẹyẹsi ni tabi nitori kini?
4 . Asẹ wa lọdọ ijọba llẹ Gẹẹsi lati gba atipo wọle:
Bi ilẹ Gẹẹsi ba kọ lati fun ẹnikẹni ni aaye atipo, ko saburu nibẹ.
Ilana yi gbe asẹ fun wn lati yala faye gba ẹni naa tabi kọ lati gba wọn wọle.
Kii se pe wọn fi saburu sugbọn bi nkan ti se ri lori gigba atipo wọle ni yẹn.
Awọn nkan mii to yẹ ni mimọ:
•Iru ẹgbẹ ti ẹni naa jẹ ọmọ ẹgbẹ rẹ, bi wọn se tobi si ati iru isẹ ti wọn n se
•Boya iru ẹni to ba gba aaye atipo yoo maa tẹsiwaju pẹlu isẹ ajafẹtọ to n se tẹlẹ ti o ba pada si Naijiria.
•Boya iru ẹgbẹ ti ẹni naa jẹ ọkan lara wọn pẹ́ka ni Naijiria tabi lẹyin odi pẹlu ẹri pe ijọba n tọ pinpin wọn.
•Iru nkan tẹni naa n se lagbo oselu ati ẹri afihan iru isẹ to n se
•Iroyin nipa mọlẹbi rẹ atiiru isẹ ti wọn n se.
















