Baba Ijesha: Iyabo Ojo ní bí wọn bá tú afurasí náà sílẹ̀, òun yóò da padà sí àtìmọ́lé

Baba Ijesha: Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ-Iyabo Ojo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbajumọ osere tiata, Iyabo Ojo ti ke gbàjare si awọn ọmọ Nàijíríà, láti gbáruku ti ọ̀rọ̀ ọmọ tí Bàbá Ijesha se iwa ibajẹ pẹlu rẹ, kí ìyà má jẹ Damilola Adekoya, ti gbogbo eniyan mọ̀ sí Princess Comedian gbé.

Nínú fídíò kan tó ṣe loju òpó instagram rẹ lalẹ ọjọru lo ti n kígbe pé, awọn ti gbọ pé àwọn kan fẹ gba ọ̀nà ẹburu yọ Baba Ijesha kuro ni àhámọ́ ọlọpaa.

Ó ní tí wọ́n bá tú Baba Ijesha sílẹ̀, òun tìkara òun yóò tun gbé lọ sí ẹ̀wọn pada àti pe ó pọn dandan ki wọ́n ṣe idajọ́ fún nílé ẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyabo Ojo ni pẹ̀lú gbogbo nǹkan ti òun ti fi ojú ohun ri nipa nǹkan ti baba Ijesha ṣe si ọmọde naa, nínú fọ́nran aworan ti Princess fún òun láànfàni láti wo, ijiya to tọ gbọdọ wa fun afurasi naa.

" Tí wọ́n bá fi Baba Ijesha silẹ̀, a ó tún mú" Gbogbo obi ni yóò dide láti gbèjà Princess lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí.

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, babaijesha/Instagram

Iyabo Ojo ni òun ń kede lórí fọ́nran náà, láti pe gbogbo àwọn tó n pete pèrò láti yọ Bàbá Ijesha kuro nínú ipò tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ bayii, pe ki wọn mase dan wo rara.

Gbajúgbajà òṣèrè náà ní kò sí bí ó ti wù kó pẹ́ tó kí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ to n wosẹ niran bayii to wọle, ó si di dandan kí àwọn ọlọpaa gbe lọ sí ilé ẹjọ́.

Ó ni gbogbo àwọn eléré tíatà tí n pe òun láti jámi lórí ọ̀rọ̀ yìí sùgbọ́n orí òtítọ́ ni òun dúró lé, ìdájọ́ òdodo si ni òun wà.

Iyabo Ojo wá ké pe Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko àti Iyawo rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn bọ̀rọ̀kìní láwùjọ, láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ki wọn si gba ìdájọ́ fún ọmọ náà.

Amin iyasọtọ kan

Iyabo Ojo ní òun yóò bá Yomi Fabiyi na tán bí owó ni lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha

Iyabo Ojo, Baba Ijesha ati Yomi Fabiyi

Ọrọ ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ ti wọn fi kan gbajumọ osere tiata lede Yoruba, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, tun ti n fa wahala miran lagbo tiata.

Idi ni pe oniruuru awọn osere tiata yii ni wọn n sọ ero wọn sori ayelujra lori isẹlẹ naa, tawọn miran si n kọju ija nla sira wọn.

Bi awọn osere tiata kan se gba pe o yẹ kawọn osere yoku se atilẹyin fun baba Ijesha ni, ti ko si yẹ ki wọn ti i maa se idajọ rẹ.

Ni awọn miran n gbara ta pe, osere tiata ti wọn fi ẹsun kan naa ti jẹwọ fun ọlọpaa nipa ẹsun yii, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin wa fun yin nipa bi osere tiata lede Yoruba meji, Iyabo Ojo ati Foluke Daramola se n ta ko ara wọn lori isẹlẹ yii.

Bakan naa ni awọn gbajumọ osere tiata Yoruba lọkunrin meji, Legemiami ati Yomi Fabiyi naa ti sọrọ nipa isẹlẹ yii, eyi to ti n fa awuyewuye.

Ki ni Yomi Fabiyi se fun Iyabo Ojo to fa epe?

Yomi Fabiyi, ninu ọrọ rẹ to gbe sori ayelujara Instagram rẹ, lo ti n tako awọn akẹẹgbẹ rẹ to ti sọrs saaju nipa Baba Ijesha , paapa awọn to n yọ suti ete si pe ki wọn sọra se.

Awọn ọrọ rẹ naa lo dabi eyi to n tako awọn ohun ti Iyabo Ojo ti sọ saaju lori ẹsun ti wsn fi kan Baba Ijesha.

Ọrọ ti Yomi Fabiyi kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

"Igba ti mo maa n ri awọn akẹẹgbẹ mi ki wọn jade sita lati sọrọ, nigba ti wọn ba fẹ bu ẹnu atẹ lu akẹẹgbẹ wọn kan to jin si koto tabi to wa ninu wahala.

Wọn gbagbọ pe ko si ẹnikẹni to le se ohunkohun fun wọn, o si yẹ ki wọn maa ranti pe Ọlọrun n bẹ o."

Ọrọ naa lo bọ si apo ibinu Iyabo Ojo, ti oun ati Yomi Fabiyi si jọ n fi atẹjisẹ sọwọ si ara wọn lori Whatsapp.

Amọ nigba to ya, Yomi gbe ọrọ naa soju opo Instagram rẹ, to si tun bi Iyabo ninu, ti onitọun si pada fun Yomi ni oko ọrọ pe oun lo n fi ọrọ to kọ naa ba wi.

Ọrọ ti Yomi Fabiyi kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

Iyabo Ojo fesi alagbara pada fun Yomi Fabiyi

Ninu esi rẹ, Iyabo ni Yomi n fi owe pe oun ni onidọti ati alaye dojuru, ti ko si le jẹ oun lo n ba wi laelae.

O wa ke si Yomi Fabiyi lati lọ wadi otitọ ọrọ nipa ohun ti Baba Ijesha se ni agọ ọlọpaa to wa ni Panti nilu Eko tabi ko lọ bi Princess, iya ọmọ naa.

"Yomi Fabiyi, to ba fẹ ba eeyan lorukọ jẹ, kii se iru emi lo mẹnuba. Bi ọrọ ba se jẹ ni mo maa n sọ, emi kii se asajẹ ma sẹ, ẹ ma jẹ ka maa pọn jẹbẹ ni akisa.

Amọ se ni Yomi Fabiyi naa tun fesi pada fun Iyabo Ojo pe ko le jẹ oun lo n ba mi, boya oun ati Baba Ijesha lo ni asamọ to n pa.

Ọrọ ti Iyabo Ojo kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

"Igi imu jinna sori. Asọ ti wọn ba ba lara egungun temi, temi lo n se. N ko ni ba ọ maa gba ọrọ bii ẹni gba igba ọti nitori mo ni iyi ati apọnle ju bayẹn lọ."

Lẹyin naa lo ba lọ se fidio kan soju opo Instagram rẹ, eyi to fi n fesi ọrọ pada ransẹ si Iyabo Ojo

Yomi Fabiyi, to ba ni asọ to mi, o ko le ni akisa to mi

Ọrọ naa ko tan rara ninu Iyabo Ojo lori esi ti Yomi Fabiyi fọ fun pada ninu fidio to se, toun naa si jade lọ se fidio mii pada loju opo Instagram rẹ lati rọ ojo epe le Yomi Fabiyi lori.

"Yomi Fabiyi, jade sita ki n sọ ọrọ si ẹ lori live fidio yii, o dabi ẹni pe ori rẹ ti yin. Iwọ ni o lawọn nnka ju mi lọ, sebi iwọ ni ọmọ isẹ baba Suwe."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyabo ni ojoojumọ ni Yomi Fabiyi maa n lọgun Baba Suwe tori pe o se oore fun.

"Yomi, ori rẹ ti daru, ori rẹ ti yin. O ni ka ma sare se ipinnu, iwọ gan lo n ba aye Baba Ijesha jẹ. Mo ti ransẹ si ninu ẹwọn to wa pẹlu."

Iyabo ni Yomi lo maa n jẹ ki awọn osere yoku maa sọ ohun to wu wọn."

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Iyabo, ẹni to n fi ibinu sọrọ lori fidio naa ni ọrọ ti iru awọn Yomi n sọ lo mu ki awọn osere yoku maa se atilẹyin fun iwa ti Baba Ijesha hu.

"Yomi Fabiyi, o n fi ara rẹ we mi, to ba ni asọ to mi, o ko le ni akisa to mi nitori nigba ti mo n jijagudu lati ko ọrọ mi jọ, nibo ni iwọ wa.

O n kọ oyinbo ofo ati isọnu, to ba jẹ ọmọ rẹ ni Baba Ijesha se iru rẹ fun, se o maa ni o fẹ wo fidio. Emi ya were gan ni, abi olori... ni ẹ ni?"

Yomi Fabiyi, maa ba ẹ na tan bi owo ni

Iyabo Ojo wa n leri leka pe Yomi Fabiyi ko ni le wọ ilu oyinbo, ti ko ba sọra, tori ohun yoo ba na tan bii owo, ti wọn yoo si fontẹ lu orukọ rẹ.

"Ẹni to ba n se atilẹyin fun afipabanilopọ, afipabanilopọ ni oun naa. Mo kuro ninu awọn to le maa fi tayin ati awọn olori... ti wọn n satilẹyin fun ọ, tẹ jọ n ba ọmọde lopọ.

Mo ti wo fidio bi Baba Ijesha se yaju si ọmọdebinrin naa, o si foju han pe baba Ijesha jẹbi ẹsun naa bajẹbajẹ, ti wọn ba fi silẹ, maa tun da pada sẹwọn.

Iyabo Ojo ni ọmọ ọdun meje si mẹjọ ni ọkunrin kọkọ bami sere oge, ti n ko si le sọ fun iya mi. Mo si ri ibi ti Baba Ijesha ti n ti ọwọ bọ ọmọde naa nidi.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

"To ba se emi ni ọrọ ọmọ yii sẹlẹ si, boya si ọmọ mi ni tabi ọmọ ọmọ mi, maa se aye onitọun basubasu, mo si n kilọ fun gbogbo ẹyin tẹ n se bẹẹ lati sọra.

O wa n fọwọ ta Yomi Fabiyi laya pe to ba to bẹẹ, ko yọju si atimole ti Baba Ijesha wa ni Panti, ti wọn ko ba ni ti mọle.

O ni "Yomi Fabiyi, mo ni ẹ lọkan tori ọmọde ti ọrọ naa kan, abi bawo ni ọrọ Baba Suwe to gbe oogun oloro Cocaine se papọ mọ ti ọmọde ti baba Ijesha n la.'

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Iyabo Ojo tun wọn epe miran jolẹ lori Baba Ijesha ati awọn eeyan to n tii lẹyin, to si tun kede pe oun ti da duro, ti oun si ti fi agbo tiata Yoruba wọn silẹ.