Ramadan: Àwọn tí kìí ṣe Mùsùlùmí sọ àǹfààní tí wọ́n n jẹ látara awẹ gbígbà

Pe aawẹ Ramadan n lọ lọwọ kii ṣe iroyin tuntun, sugbọn nkan kan to jẹ iyalẹnu ni pe awọn eeyan kan ti kii ṣe ẹlẹ́sìn Musulumi naa n gba awẹ naa.
Eyi gan-an lo difa fun awọn kan ti kii ṣe ẹlẹ́sìn Musulumi lorilẹ-ede Sri Lanka, àmọ́ ti wọn n gba awẹ Ramadan nitori oore to n ṣe fun wọn.
Ẹsin Buddha lo gbajumọ julọ ni Sri Lanka, lẹyin naa ni ẹsin Katoliiki ati Musilimu.
Nitori naa lo ṣe jẹ iyalẹnu nigba ti ọdọmọkunrin oloṣelu kan lorilẹ-ede naa, kede pe oun n gba awẹ Ramadan.
Rehan Jayawickreme ko jẹun ọ̀sán lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin ti Ramadan ti bẹrẹ, bẹ́ẹ̀ si ni ko mu.
Nkan miran to tun jẹ ki igbesẹ rẹ jẹ iyalẹnu ni pe, ọpọlọpọ eeyan ni kii fi oju're wo àwọn musulumi ni Sri Lanka.
Eyi ko sẹyin bi awọn alakatakiti ẹṣin islam ṣe kọlu àwọn sọọsi lasiko ọdún Ajinde lọdun meji sẹyin.
Ikọlu naa mu ẹ̀mí eeyan lọ, ti awọn kan si tun farapa.
Yatọ si eyi, ọjọ gan-an ti awọn eeyan Sinhala ati Tamil n ṣe ayẹyẹ ibẹrẹ ọdun tuntun, naa ni Ramadan maa n bẹrẹ.
Ki lo le mu ki ẹlẹ́sìn Buddha ma a gba awẹ Ramadan?
Rehan Jayawickreme sọ pe oun gba awẹ naa lati ṣe atilẹyin fun awọn musulumi nitori bi awọn eeyan ṣe n dẹyẹ si wọn nitori ikọlu to waye ọhun.
Jayawickreme nikan kọ ni ẹlẹ́sìn miran to n gba awẹ Ramadan ni Sri Lanka.
Marianne David, akọroyin kan to n gbe ni olu ilu Sri Lanka, Colombo sọ pe, oun naa ma n gba awẹ Ramadan.
O ni awẹ naa ma n fun oun ni ifọkanbalẹ, aanu, alaafia ati ìmọ̀, to si tun ma n kọ ni ẹkọ nípa ìtọrẹ aanu, paapaa fun awọn ti ebi ń pa.
Ọpọlọpọ eeyan si lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu Jayawickreme pé, nitori ìbò lo ṣe n ṣe iṣe musulumi.
Àmọ́, oun naa dahun pe, kii ṣe pe oun fẹ di ẹlẹ́sìn Islam. O ni oun n ṣe nitori pe oun korira idẹyẹsi.
Nadyne Parr to jẹ Kristẹni lati ilẹ America paapa sọ pe oun kii fi Ramadan ṣeré.
Ilu Michigan ni Parr ti n sisẹ olukọ ati Onkọwe.
O ni ifọwọsowọpọ ti Ramadan maa n fi si aarin oriṣiriṣi ẹ̀sìn ati àṣà, lo jẹ iwuri fun oun.
Ati pe asiko naa ma n mu oun sunmọ Ọlọ́run si.





















