Ramadan: Kíni ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ si àgọ ara rẹ̀ ti o bá n gbààwẹ

AWORAN OUNJE LASIKO AWE

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Ahmen Khawaja
    • Role, BBC World Service

Lọ́dọọdún àwọn musulumi jákejado àgbáye a máa gbààwẹ láti ààrọ di alẹ́ fún ọgbọ̀n ọjọ gẹ́gẹ́ bii ètò Ramadan

Ní ǹkan bi ọdun diẹ̀ sẹ́yìn àsìkò òòrun ni oṣù ààwẹ máa ń wáyé, èyí yóò si wáye ni ǹkan bíi ọjọ mẹ́rindinlogun inu oṣù káàrún ọdun yìí ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (UK) èyí túmọ̀ si pé ojú ọjọ yóò maa gùn ju bí o ti yẹ lọ.

Eyí túmọ si pé àwọn orilẹ̀-èdè míràn, bii Norway yóò maa gbààwẹ fún odidi ogun wákàti lójoojumọ ninu ọdun yìí.

Ǹjẹ ó dára fún ìlera rẹ? Eyí ni àwọn ǹkan to maaá n ṣẹlẹ̀ si ara rẹ ti ó ba gba ààwẹ ọgbọ̀n ọjọ́.

Doughnuts

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lásìkò ààwẹ, ara rẹ yóò kọ́kọ́ sàmúlò súgà inu ẹjẹ rẹ láti fún ẹdọ ni àgbara to nilo.

Asiko to níra jù- àwọn ọjọ akọkọ ti ààwẹ ba bẹ̀rẹ̀

Ìmọ̀ fi yeni pe ara kìí wọ inu ààwẹ ti kò ba ti pe w;akàti mẹ́jọ lẹ́yìn ounjẹ ti ènìyàn ba jẹ kẹ́yìn.

Èyí ni àsìkò ti ifun ba ti ṣe àmúlò àswọn ounjẹ to kù ni àra.

Bí ààwẹ náà ṣe ń tẹ̀síwájú, tí gbogbo àwọn súgà inu ẹ̀dọ̀ ba ti tán, ọ̀rá ara ni yóò fi ààbọ si láti pése agbára fún ara ninu ààwẹ

Hungry man sits at a table with plate, knife and fork Ọkunrin kan ti ebi n pa joko si ori tabili pẹlu sibi àti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lẹyin àwọn ọjọ díẹ̀ ti ààwẹ ba ti bẹ̀rẹ̀ to sábà máa ń nira, nágbà ti ara bá ti n sinlẹ̀ fún mimọ pe ara ń gba ààwẹ ti ara yóò ti mọ pe oun gba ààwẹ.

Tí ara ba ti bẹ̀rẹ̀ si ni ń jo ọ̀rá dànù, èyí máà ń ṣe ìrànwọ fún ara láti dínku ti ẹni náà ba sanra, èyí a si maa mu adinku ba àisàn ìtọ̀ súgà.

Ẹ̀wẹ̀, àdińkù nínú súgà inú ẹ̀jẹ̀ yìí lo máá n fa ki ara maa hù

Àsìkò yìí ni ebi a maa pa eniyan gan-an

Ó ṣeéṣe kí ki ó máa ni ori fifọ, ojú síṣú, kí èbi maa gbe èniyan tabi ki ẹnu eniyan maa rùn.

Ẹ ṣọ́ra kí omi maa gbẹ lára- Èyi láàrin ọjọ mẹ́ta si ọjọ Meje(Day 3-7)

Bí ara ba ṣe ń gbàá pe ààwẹ ti n mọ oun lára, àwọn ọ̀rá ara a máá yíí si 'sgà inú ẹjẹ.

A gbọdọ̀ máa ṣe ìdá padà Àìjẹ, àìmu ààrin ààwẹ náà nítori pe líla òògun le mú ki omi ara ó gbẹ

Man drinking water

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Omi mimu ṣe patàkì lásiko ààwẹ páàjùlọ lásiko òòrun

Awọn ounje ti e gbodo maa je gbodo je ounje afaralokun ati eyi to ni ọ̀rá

O ṣe pàtàkì láti maa jẹ ounjẹ to ni gbogbo èròja aṣara lóore.

O ti n mọ́ra bayìí (Day 8-15)

Ni ipele kẹta, ó yẹ ki iyatọ ti maa ba ara nítori, ara ti mọoo pe oun gba ààwẹ báyìí.

Dokita onimọ nipa itoju pajawiri ni ile iwosan Cambridge Razeen Marhroof sàlàye pe àwọn anfani miran tun wá ninu ki ènìyàn máá gba ààwẹ.

Ounje alaranbara lori tabili

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ti ènìyàn bá n jẹ ǹkan ti orá ba pọju, o ṣeeṣe ki àwọn ǹkan to ba bàjẹ lára maa le ṣe atunse ara.

"Ni òunjẹ ojoojumọ a máa n jẹ awọn ounje ti ọ́rá wọn pọ̀, eyi ti om si n ṣe akoba fun ara láti ṣe àwọn atunṣe to tọ si agọ ara fura rẹ"

" Awọn ǹkan wọnyii ni ààwẹ maa ń ṣe lára ti yóò si ma mú gbogbo nkan bọ sipo"

" Nítori náà ààwẹ máa n ṣe ara láàfàni, o maa n ṣe iwosan bákàn náà lo n dena àìsàn."

Fífọ idọti ara (Day 16-30)

Ni kété ti ààwẹ ba ti dá si meji, gbogbo agọ ara ni yóò ti duro deede ni igbaradi fun ààwẹ náà.

Ẹdọ̀ fóóró, ẹ̀dọ̀, kídìnrin, àti àwọ ara yóò maa fọ idọti wọn kuro.