Ramadan 2024 : Wo nǹkan márùn ún tó ṣe kókó àti èèwọ̀ fún aláàwẹ̀

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency
Oṣu apọnle fawọn Musulumi, oṣu Ramadan mii tun ti wọle de.
Oṣu pataki, alapọnle fawọn musulumi lati tun fi kun fun ijọsin ati iwa rere.
Lorileede Naijiria ati lawọn orileede mii lagbaye, aawẹ Ramadan ti gbera sọ lẹyin ikede lọdọ awọn olori musulumi.
Ninu oṣu yii, awọn musulumi maa n pa ẹnu ati abẹ mọ lati owurọ kutu titi di igba ti oorun yoo fi wọ.
Sultan ilu Sokoto, Abubakar Saad to jẹ olori musulumi ni Naijiiria lo kede ibẹrẹ aawẹ tọdun yi.
Bayii ti aawẹ ti wa bẹrẹ, ki lawọn nkan marun un to yẹ ki musulumi ṣe lati le gbadun awẹ naa bo ti ṣe yẹ.
Ohun marun to yẹ ki Musulumi se lasiko Aawẹ:
Ri wi pe o mu omi daada
Lootọ, awẹ ni nnkan ṣe pẹlu ki eeyan maa ṣe mu tabi jẹun ṣugbọn awọn onimọ sọ pe, ti alaawẹ ba fẹ gbadun awẹ, o di dandan ko mu omi daada.
Lasiko ti eeyan ba n jẹ saari tabi lasiko iṣinu, omi mumu yoo jẹ ki agọ ara eeyan ṣe iṣẹ bo ti ṣe yẹ lasiko to ba n gba awẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Omi amuju naa ko daa, ki a ma gbagbe pe niwọntunwọnsi lo yẹ ki a ṣe nkan.
Jẹ awọn ounjẹ to n fun ara lokun, ko si yago fun iyọ pupọ
Bi o ba di asiko saari jijẹ, amọran fawọn alaawẹ ni pe ki wọn jẹ ounjẹ ti yoo fun ara lokun.
Yatọ si eleyi, wọn ni ki iru ounjẹ naa jẹ eleyi ti yoo tete da lara wọn ki wọn si ma ṣe jẹ ki iyọ pọ ninu rẹ.

Bi eeyan ba n jẹun, ko jẹ ni iwọntun wọnsi, ko ma jẹ ounjẹ pupọ nitori eleyi le ṣe akoba fun ara
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ṣe eto bi wa ṣe lo asiko rẹ daada
Iye wakati ti alaawẹ yoo fi gba aawẹ ko yẹ ko ju wakati mejila si mẹtala lọ.
Bi eeyan ko ba lo akoko yii daada, yoo dabi pe gbogbo ọjọ lo fi n gba awẹ ni.
Ri wi pe o ṣeto awọn iṣẹ ati iṣẹ laada lasiko awẹ bi kike alukurani, gbigbọ waasi ati wiwa pẹlu mọlẹbi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo ba di looru to yẹ ko ji fun Tahajjud naa, la asiko to ba fẹ fi ji kalẹ, ki o ba le ni eto.
Ri wi pe o ṣun daadaa
Oorun a maa jẹ ki ara bọ sipo pada lẹyin ti eeyan ba ṣe wahala.
Pupọ alawẹ ni kii sun daada, ti eleyi si maa mu ki irẹwẹsi kan maa ba wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi o ba ri pe o pari gbogbo iṣẹ to y ki o ṣe ti asiko si wa fun ẹ, tara nara silẹ ko sun ki alaafia ba le ba ara rẹ.
Ṣọ ọrọ to n jade lẹnu rẹ
Yiyago fun ounjẹ ati omi mimu to fi mọ ṣiṣọ gbolohun to ba n jade lẹnu alaawẹ jẹ ọna kan gbogi ti alawẹ gbọdọ mojuto.
Irọ pipa, isọkusọ, sisọ ọrọ karimi wa lara awọn ọna ti alaawẹ le fi padanu oore to wa ninu awẹ gbigba.
Lati le dena eleyi, awọn onimọ ẹsin ni ki awọn musulumi sọ ọrọ ẹnu wọn ati iwa wọn.
Awọ nkan marun un toyẹ ki alaawẹ yago fun:
- Ibalopọ lọsan aawẹ
- Jijẹun ju lasiko iṣinu tabi ni asiko saari
- Lilọra lati sinu ti asiko ba to
- Sisọrọ eeyan lẹyin lasiko aawẹ maa n din laada ku
- Ṣiṣe iwa ṣekarimi pẹlu aawẹ tabi iṣẹ oloore mii ta ba ṣe ninu oṣu Ramadan















