Funke Etti: Mo gbádùn ẹ̀sìn Islam nígbà kan rí, ṣùgbọ́n mo ti di ọmọlẹ́yìn Kristi báyìí

Funke Etti

Oríṣun àwòrán, iamfunkeetti/nstagram

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba lobinrin, Funke Etti ti ṣalaye bo ṣe pa ẹsin da, lati Musulumi si Kristẹni.

Funke Etti sọ pe oun gba ẹsin Kristẹni ninu ijọ Irapada, RCCG, ni nnkan bii ọdun mejila sẹyin.

Oṣere naa ni, bo tilẹ jẹ pe oun gbadun akoko oun gẹgẹ bii Musulumi ṣugbọn oun yipada di Kristẹni nigba ti akoko to.

O ni "Mo wa ni olu ijọ RCCG lọjọ naa lọhun nigba ti olori ijọ naa, pasitọ E.A. Adeboye pari iwaasu rẹ, to si kede pe ki gbogbo awọn to ba fẹ fi aye wọn fun Jesu maa bọ niwaju, mo si ṣe bẹẹ."

"Lẹyin ti mo jade siwaju tan ni mo tọrọ idariji ẹṣẹ mi, ti mo si di atunbi lọwọ kan naa."

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Funke ṣalaye pe ẹlẹsin Musulumi ni baba oun, ti iya oun si jẹ ọmọlẹyin Kristi, ṣugbọn ko si eyikeyi ninu awọn mejeji to fi ipa mu oun lati ṣe ẹsin tirẹ.

O ni oun funra oun loun yan ẹsin ti oun n ṣe lati ilẹ wa.

O ni "Nigba ti mo jẹ Musulumi, mo maa n gbadura nigba marun un lojumọ, mo si tun maa n gba aawẹ ni akoko to yẹ, eyii to jẹ ohun ti mo gbadun."

Àkọlé fídíò, Femi Adebayo: Ẹyin ọ̀dọ́, ẹ káàbọ̀ ságbo ilé Tíátà

O wa pari ọrọ rẹ pe, ni bayii ti oun ti di ọmọlẹyin Kristi, gbogbo ohun ti awọn Kristẹni n ṣe ni oun naa n ba wọn ṣe.