Smart Adeyemi: Bí àwọn agbebọn ṣe ń pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló pa mí lẹ́kún

Sẹnetọ Smart Adeyemi

Oríṣun àwòrán, @SenSmartAdeyemi

Sẹnetọ Smart Adeyẹmi ti ṣalaye pe bi ipaniyan ṣe di tọrọ fọnkale ni Naijiria lọwọlọwọ bayii, eyi to ni o gba omije loju oun lasiko ti oun fi n sọrọ nibi ijoko ile aṣofin agba lọjọ Iṣẹgun.

Sẹnetọ Adeyẹmi to bu omije soju lasiko to n da ṣi ọrọ wahala eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria, eyi ti ile gbe yẹwo ni, irufẹ ipaniyan to n waye bayii ni Naijiria ko fẹẹ ni ẹlẹgbẹ, lati igba ti wọn ti tẹẹ do.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Adeyẹmi woye pe laijẹ pe Naijiria n jagun lọwọ, iye ẹmi to n padanu lorilẹede yii kọja eyi ti awọn aṣiwaju gbọdọ mojuto.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lori itaporogan to waye laarin oun ati akẹgbẹ rẹ, Sẹnetọ Rẹmi Tinubu, lori pe ọrọ rẹ dabi ọrọ alatako, Sẹnetọ Adeyẹmi ni ọrọ to wa nilẹ bayii ti kuro ni ọrọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ, ti gbogbo awọn aṣofin si gbọdọ jigiri lori rẹ.

Awọn ologun n yẹ ọsẹ ti awọn agbebọn se wo

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

O ni oun ko lee sọ san an pe ijọba aarẹ Buhari ti ja araalu kulẹ nitoripe awọn nnkan ti wọn ṣe to dara pẹlu wa.

Sugbọn o ni koko agbekalẹ iṣejọba fun araalu, eyi to jẹ aabo ẹmi ati dukia ni ijọba Buhari ti ja kulẹ, ti o si nilo ki o ji giri wa nnkan ṣe si.

Sẹnetọ Adeyẹmi to nṣe oju ẹkun idibo apapọ iwọ-oorun Kogi (Kogi West) ni lootọ Buhari lee jẹri sii pe oun wa lara awọn aṣofin to n fi igba gbogbo tii lẹyin.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Amọ o ni sibẹ, nibi ti hilahilo ọrọ aabo de bayii, awọn aṣiwaju ko gbọdọ fi ọrọ naa ṣe egbo ile nitori iye ẹmi to n ṣofo ni Naijiria bayii pakasọ.

Amin iyasọtọ kan

Remi Tinubu rí ìbínú ọmọ Nàíjíríà lórí bó ṣe tọwọ́ òṣèlú bọ ètò ààbò

Oloye Remi Tinubu

Oríṣun àwòrán, @RemiTinubu

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, orukọ Remi Tinubu lo leke tente lori ayelujara lorilẹede Naijiria ni owurọ Ọjọọru, lẹyin ti fidio kan safihan gbolohun ti Remi Tinubu sọ lori eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Sẹnetọ to n soju ẹkun idibo Iwọ oorun ipinlẹ Kogi, Smart Adeyemi lo n fi itara sọrọ lori eto aabo to ti dẹnukọlẹ ni Naijiria, o ni ki pe ki aarẹ Buhari o wa nkan ṣe si ni kiakia.

Lasiko ti Adeyemi n sọrọ lọwọ ni Remi Tinubu, to n ṣoju ẹkun aarin gbungun ipinlẹ Eko, nile Igbimọ Aṣofin agba ọhun sọ wi pe, lo n bi akẹẹgbẹ rẹ naa pe se o si wa ninu ẹgbẹ oselu PDP ni?

Bakan naa ni Remi tun n Adeyemi pe se aguntan to da asọ ikooko bora ni? Ọrọ rẹ yii si lo bi ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ninu.

Bawo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ ni Ile Aṣofin Agba ni Ọjọ Iṣẹgun?

Senato Sani Musa lo ke gbare pẹlu aba to gbe sita pe awọn agbesunmọmi Boko Haram ti gbakoso ijọba ibilẹ mẹta ni ipinlẹ Niger, ti wọn si ti gbe asia wọn soke sibẹ lati jẹ olori le awọn eniyan lori.

Lasiko yii ni Sẹnatọ Smart Adeyemi dide, to si fi itara sọrọ wi pe eto aabo lorilẹede Naijiria ti dẹnukọlẹ patapata.

Ninu ọrọ rẹ, Adeyemi, ẹni to n fi omije sọrọ ni o ṣeni laanu wi pe, awọn eniyan paapaa ijọba, n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu eto aabo to ti dẹnukọlẹ kaakiri nitori ọpọ ọmọ Naijiria ni ẹmi wọn ti sọnu sinu ijamba ikọlu kaakiri.

''Nigba kan ri, mo le tẹ ọkọ leti lati ibi ti mo wa lọ si Maiduguri lai si wahala, amọ ọrọ ko ri bẹẹ mọ, ko si ọkan ẹni to balẹ lati wa ọkọ lati ilu kan si omiran''

''Aarẹ! Ina njo lori papa lorilẹede Naijiria, asiko si ti to lati sọ ododo ọrọ lai fi ti ọrọ oṣelu bọ ọ, nitori ọpọ ẹ̣mi lo n sọnu kaakiri ẹya ati ẹkun Naijiria''

''Ẹ kesi awọn orilẹede lagbaye lati wa ran wa lọwọ, ki ẹ fi ti igberaga silẹ, nitori apa ẹnikẹni ni Naijiria ko ka ọrọ to wa nilẹ yii mọ''

Kini Remi Tinubu sọ to bi awọn ọmọ Naijiria ninu?

Lasiko ti Sẹnatọ Adeyemi n fi itara sọrọ lọwọ lori eto aabo naa, ti omije si n bọ loju rẹ, ni fidio safihan Remi Tinubu to n sọrọ labẹlẹ.

Ninu ọrọ to sọ, Remi Tinubu ni ''Ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹ ni? Abi ikooko to wọ aṣọ aguntan ni iwọ n ṣe ni?

Amọ, Smart Adeyemi ko tilẹ fun Remi Tinubu lesi, to si bẹrẹ si sọrọ fitafita pe, asiko ti to lati beere iranwọ ni oke okun lori eto aabo, nitori ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu Naira ni ijọba ti na, ti ko si si aṣeyọri kankan.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Awọn ọmọ Naijiria sọ oko ọrọ si Remi Tinubu

Loju ọpọ Twitter ni awọn ọmọ Naijiria ti fi ero wọn han si itakurosọ to waye ni Ile Igbimọ Asofin Agba naa ni Ọjọ Iṣẹgun.

Ọpọlọpọ awọn to sọrọ ni, ko yẹ ki Remi Tinubu ti ọrọ oṣelu bo ọrọ eto aabo to mẹhẹ kaakiri ẹkun Naijiria, ati wi pe iwa buruku gba a ni arabinrin naa wu.

Awọn miran ni Remi Tinubu pẹlu iwa rẹ ko le e jẹ iyawo aarẹ lorilẹede Naijiria, ti ọkọ rẹ ba dije dupo ni ọdun 2023, nitori wọn ko ni dibo fun un.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Bakan naa ni awọn miran ni Remi Tinubu gbọdọ bẹbẹ, ko si tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria, nitori ọrọ aibikita to sọ nipa bi ẹ̣mi awọ̣n ọmọ Naijiria ṣe n sọfo lojoojumọ nitori eto aabo ti ko muna doko.

Bi o tilẹ jẹ pe ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu to jẹ ọkọ Remi Tinubu ko tii sọ ni gbangba pe, oun yoo dije dupo aarẹ ni ọdun 2023, ọpọlọpọ eniyan lo n sọ wi pe arakunrin ọhun ti n gbe igbesẹ to jọ bẹẹ.