Budo koko water scarcity: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Budo koko, Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu
Ko si orisun omi kankan ni ilu Budo koko nijoba ibilẹ Asa nipinlẹ Kwara, bẹẹ a ni ìjọba!
Ilu Budo koko yii jẹ ilu ti gbogbo awọn obinrin wọn ti sa lọ tan nitori iṣoro omi ti ko si.

Ilu yii wa ni ijọba ibilẹ Asa nitosi Ilorin ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.
Alhaji Saka Alabi, ọkan lara awọn to ba BBC sọro ni ohun gbogbo ri su wọn.
O ni ilu miran ni wọn ti lọ n bimọ nitori ko si omi ti wọn yoo fi wẹ ikoko jojolo.

Ogbeni Sunmonu Ishola to jẹ Mogaji Budo koko ni anabi lo ku ti wọn n bẹ nitori ọrọ omi.
Wọn ti bẹ ijọba o si ti su wọn.
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- Ọgbà wèrè àti ilé aṣẹ́wó nilé ẹni tí kò lówó tó tún fẹ́ ìyàwó mẹ́rin- Sheik Akewugbagold
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
Imaamu Budo Ikoko, Alhaji Saka Alabi ni iṣoro aisi omi ti fẹ tu ilu yii ka ti awọn si ti fẹ ṣilọ silu mii nitori pe o ti n di ahoro.
O ni ẹẹkan lọsẹ ni ọpọ wọn maa n wẹ.
Wọn ni #100 ni jala kẹẹgi omi kan ni ilu keji si wọn, wọn yoo si wọ ọkada #200 lọ ati #200 pada bọ wa si Budo koko.

Awọn ara ilu darukọ awọn alaga kansu ati awọn oloṣelu ti wọn ti kan koda wọn tun darukọ awọn to ti ṣe ijọba sẹyin ti wọn n ṣeleri pe: Mo n bọ, mo n bọ naa ni wọn n sọ!
Wọn ni awọn ti ke gbajare de ọdọ ijọba ipinlẹ Kwara ṣugbọn ko tii si nkankan.
- Wo àtúpalẹ̀ nkan tí òmìnira tí àwọn gómìnà fi ọwọ́ sí fún ẹ̀ka ìdájọ́ Naijiria túmọ̀ sí
- Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
- Olufon ti ilu Ifon-Orolu, Ọba Almarouf Adekunle Magbagbeola ti wàjà
- Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de
Wọn n rawọ ẹbẹ si awọn eeyan ipinlẹ Kwara lati ba wọn bẹ awon ti ọrọ kan lati wa ojutu si iṣoro aisi omi to n gba ẹbọ lọwọ a\won eniayn Budo koko nijọba ibile Asa ni ipinlẹ Kwara bayii
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Ṣé lóòtọ́ ni Sotayo Gaga ti di ìyá Ọba nílẹ̀ Hausa?
- Wa kọ́ síi nípa ẹ̀yà ara rẹ̀ tí ò ń lò fún ìró èdè pípè lórí Akọmọlede tòní




