Islam, Sheik Taofeeq Akewugbagold: Ọgbà wèrè àti ilé aṣẹ́wó nilé ẹni tí kò lówó tó tún fẹ́ ìyàwó mẹ́rin

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ọgbà wèrè àti ilé aṣẹ́wó nilé ẹni tí kò lówó tó tún fẹ́ ìyàwómẹ́rin- Sheik Akewugbagold

Sheik Akewugbagold ṣalaye pe: Iyawo kan ni dandan fun ọkunrin ninu ẹsin Islam.

Bakan naa ni aafa yii ni ko si nkan to buru ninu Islam pe ọkunrin kan fẹ iyawo meji si mẹrin lọjọ kan ṣoṣo.

Aafa ni 'Kọndisọn' lo gbe iyawo pupọ fifẹ jade ninu ẹsin Islam.

Sheik Akeugbagold ni pe: Owó nini lo ṣe pataki julọ lati fẹ iyawo mẹrin ninun Islam ati agbara lati ba wọn sun bi o ṣe yẹ lasiko

Akewugbagold

Oríṣun àwòrán, @Akehugbagold

Àkọlé àwòrán, Sheik Akehugbagold nipa iyawo mẹrin ninu Islam

Sheik Akewugbagold ni pe nini iyawo meji si mẹrin ko ba ẹsin jẹ ninu Islam ṣugbon ofin mọkanla lo gbọdọ tẹlẹ ninu sharia ki o ma ba jébi.

O ni Anabi ko faaye gba ṣiṣe 'Fadá' rara ninu Islam

Ati pe o san, lati ni iyawo pupọ ju iyawo kan nile pẹlu àlè pupọ nigboro.

Wo idi ti Olorun ṣe faaye gba iyawo mẹrin ninu Islam ninu ifọrọwerọ pẹlu Sheik Akewugbagold yii lẹkunrẹrẹ.

Ṣe o mọ pe o maa ni 'Stroke' ti o ba ku ti o ko ba ṣe deede laarin awọn iyawo mẹrin ti o fẹ sile?