Buhari ní àìmú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn lò ló ń fa ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency
Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn musulumi Naijiria lati maṣe gbagbe ẹkọ ti wọn kọ lasiko aawẹ oṣu Ramadan to pari.
Ninu ọrọ ikinni ku ọdun itunu aawẹ to fi ranṣẹ sawọn musulumi lorilẹ-ede Naijiria ni Aarẹ ti sọ ọrọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ Buhari ni ọpagun lo yẹ ki ẹsin jẹ fun iwa awọn to ba gbagbọ lati ṣe atọna fun igbe aye wọn ni gbangba ati ni kọọrọ.
"Bi awọn eeyan ba gba ẹkọ ẹsin wọn laaye lati maa ṣe atọna fun ihuwasi wọn, awọn iṣoro bii iwa ijẹkujẹ eleyii to n ko owo ilu lọ si apo awọn eeyan kan yoo ti di itan lawujọ."
Aarẹ Buhari ni lẹyin ti wọn ti pari 'oṣu to ni ipa pataki nipa ti ẹmi lori ifara ẹni jin' yii, ki awọn musulumi o ronu lori pataki oṣu Ramadan ki wọn le di aṣoju rere fun ẹsin Islam ni gbogbo igba.










