World environment day: MOSOP ní Ààrẹ Buhari kò sòótọ́ lórí àfọ̀mọ́ Ogoni

Koriko ti wahala ayika ti da laamu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, MOSOP ní nńkan ò rọgbọ fún àwọn èèyàn ẹkùn Niger Delta, paapaajulọ agbègbè Ogoni

Ẹgbẹ kan to n ja fun igbayegbadun awọn eeyan agbegbe ogoni lẹkun Niger Delta, MOSOP, ti ke si ijọba apapọ ati awọn ileeṣẹ awapo rọbi tọrọ kan lati tubọ kona mọ eto afọmọ agbegbe Ogoni ni ibamu pẹlu abajade iwadi ajs to n mojuto atunṣẹ idibajẹ to waye nipasẹ epo rọbi, HYPREP.

Aarẹ ẹgbẹ MOSOP, Legbosi Pyagbara to pe ipe yii ninu ọrọ ayajọ idaabo bo ayika ti ọdun 2018.

O ni akori ayajọ naa to fọnrere wahala ti ike n koba ayika jẹ ohun to pe akiyesi gbogbo eeyan si wahala to n lọ layika.

Awọn eeyan n fori ru ẹru ni ibudo ikẹgbin si kan nilu Eko

Oríṣun àwòrán, Eti-Inyene Godwin @sirinyenephotography

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ MOSOP ko si ootọ ninu ọrọ si Aarẹ Buhari to sọ laipẹ yii pe isẹ afọmọ agbegbe Ogoni "nlọ ni sẹpẹsẹpẹ."

O ni bi ijọba agbaye ba lee maa lọgun pe akoba ti ike n ṣe fun ayika pọ lọ jara, akoba ti epo rọbi n ṣe fun ayika ko ṣee maa fi ẹnu sọ

Gẹgẹ bii aarẹ MOSOP naa ṣe sọ, akoba epo rọbi yii ni awọn eeyan agbegbe Ogoni n ba finra eleyi to nilo apewo ijọba atawọn ileeṣẹ gbogbo ti ọrọ kan.

Ẹwẹ, Ẹgbẹ MOSOP ati ajọ ajafẹtọ kan Social Development Integrated Centre (Social Action) ti koro oju si Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lori ọrọ kan to sọ laipẹ yii pe isẹ afọmọ agbegbe Ogoni "nlọ ni sẹpẹsẹpẹ."

Ọpa epo rọbi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ MOSOP akoba epo rọbi pọ pupọ fun ayika awọn eeyan agbegbe Ogoni

Awọn ẹgbẹ mejeeji ọhun tun kọminu pe ninu iwoye awọn, ko jọ bi ẹni pe ileeṣẹ ọrọ ayika nijọba apapọ ati ileeṣẹ to n mojuto atunṣẹ idibajẹ to waye nipasẹ epo rọbi, HYPREP ṣetan lati ṣe afọmọ idibajẹ ọrọ ayika to sodo si agbegbe Niger Delta.

Agbenusọ fun MOSOP, Fegalo Nsuke tọka si ọrọ ti aarẹ Buhari sọ ninu ọrọ ayajọ ijọba tiwantiwa to ka fawọn ọmọ orilẹede yii ninu eyi to ti sọ pe eto afọmọ agbegbe Ogoni n lọ "bi o ti tọ ati bi o ti yẹ."

O ni ọwọ ti iku fi n wọle mu tọmọde tagba lọ lagbegbe Ogoni, papaa ni ileto Bodo nijọba ibilẹ Gokana nibi ti o ni o kere mọ, lọsẹ kan, eeyan mẹwa yoo dagbere faye, n kọ ọpọ lominu.