nPDP: Iléeṣẹ́ ààrẹ, APC ń dúnkokò mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ wa

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Awọn adari ẹgbẹ kan to jẹ agbarijọpọ awọn oloṣelu to fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ darapọ mọ APC lọdun diẹ sẹyin ti wọn n pe ni nPDP ti kede pe awọn n yọwọ kuro ninu ijiroro to n waye pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ati ileeṣẹ aarẹ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni ọjọ aje, olori ẹgbẹ naa, Abubakar baraje ni awọn pinnu lati yọwọ kuro ninu ifikuluku naa lẹyin apero lori ohun ti oju awọn ọmọ ẹgbẹ naa n ri labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Abubakar Baraje fẹsun kan ileeṣẹ aarẹ pe iwa o jẹ nile oro jẹ nile eegun lo n hu lori ọrọ naa ati pe ko ṣootọ lori ifikuluku rẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lara awọn ohun to tọka si gẹgẹ bii ara iwa aiṣootọ ileeṣẹ aarẹ ni ti iwe ipe ti ileeṣẹ Ọlọpa fi pe aarẹ ile aṣofin apapọ, Bukọla Saraki.
Ẹgbẹ nPDP wa lara awọn ẹgbẹ to so pọ di igun ile fun ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju eto idibo 2015.
Ede aiyede to waye laarin ẹgbẹ ẹgbẹ oṣelu PDP to n ṣejọba nigba naa lo faa ti awọn saraki-saraki ẹgbẹ oṣelu naa kan fi digba di agbọn wọn kuro lẹgbẹ oṣelu naa wa darapọ mọ awọn igun oṣelu miran lati da ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.








