Nigeria Loan Status: Ẹ yéé yá ìjọba Nàìjíríà lówó mọ́- Akintoye Ukiwe àti àwọn 125 mííràn kọ̀wé sí World Bank

Nigeria Loan Status: Ẹ yéé yá ìjọba Nàìjíríà lówó mọ́- Akintoye Ukiwe àti àwọn 125 mííràn kọ̀wé sí World Bank

Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kìlọ fún àwọn orílẹ̀-èdè àgbéye láti dẹ́kún yíyá ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lówó

Àwọn àgbààgbà tó tó mọ́kàndínládóje ló jọ búwọlu iwé òfin tó pé fún ipinya Nàìjíríà èyí tí wọ́n gbékalẹ̀ lọjọ́ kẹrindinlógun oṣù kejila ọdun 2020.

Lárà àwọn ènìyàn jànkajànkàn tó buwọ́lùwé náà ni gómìnà ìpińlẹ̀ Plateau nígbà kan ri, Jonah Jang ọjọgbọ̀n banji Akintoye àti ààrẹ Onaheze Ndigbo nígbà kan rí olóyè Nnia Nwodo to fi mọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Yusuf Turaki àti àwọn mẹ́rìnlélọ́gọ́fà mííràn.

Nínú àtẹ̀jáde wọ́n ní wọ́n ti kìlọ fún Bánkì àgbáyé, IMF, àjọ ìṣọkàn agbáyé, Ajọ iṣokàn ilẹ̀ Afirika, Ajọ ìsòkàn Yuroopu, ilẹ̀ Amẹrika, orílẹ̀-ede Faranse, ìjọba ilẹ̀ China àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti dẹ́kun yíyí Nàìjíríà lówó mọ́.

Wọ́n tẹ̀pẹlẹ mọ pé, kò sí ìgbàgbọ́ nínú Nàìjíríà mọ́ nítórí ti ìbáṣepọ̀ kò bá ti dámaràn mọ́ irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ kìí ṣe nǹkan ti ènìyàn ń kọbiara sí bí láti yáwọ fún.

Nínú àtẹjáde tí alága ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó fún àwọn ọmọ Nàìjírà tó fẹ́ dádúrò, NINAS Otuba Folashade Olukoya fọwọ́sí ló tí ṣàlàyé pé ìròyìn tó n tẹ ẹgbẹ́ NINAS lọ́wọ́ ni pé ìjọba Nàìjíríà tún ti fẹ́ yá owó mííràn.

" A tún fẹ́ fi àsìkò yìí rán àwọn orílede tókù létí pé, ọ̀rọ̀ Nàìjírìa kìí ṣe àjùmọ̀ ṣe mọ́ gẹ́gk bí wọ́n ṣe ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lásìkò àpérò àwọn oníròyin tó wáyé nínú oṣù kẹta.

Wọ́n fi kún pé àwọn orílẹ̀-èdè tó fẹ́ pín kò ni san nínú owó tí Nàìjíríà ń fi ojojúmọ́ yá tàbi gbà láti fí òun ìní wọ́n dúró fún gbèsè tí Nàìjírìa jẹ.