Dino Melaye vs Iyabo Ojo: Sẹ́nétọ̀ ní lórí irọ́ ní ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló wà láàrin òun àtàwọn òṣèré tíátà

Aworan Dino Melaye ati Iyabọ Ojo

Oríṣun àwòrán, other

Laipẹ yii ni fidio kan gbode lori ayelujara, ninu eyi ti ohun gbajumọ oṣere tiata ni, Iyabọ Ojo ti n jade bi eyi to wa lori ipe ago, to si n fi gbajumọ Sẹnetọ ati ọmọ jayejaye nni, Dino Melaye ṣepe.

Iyabọ Ojo n sọ ninu fọnran naa pe, Sẹnetọ Melaye n parọ fun awọn ọmọbinrin miran pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun pẹlu rẹ, nigba to si jẹ wi pe adehun ifẹ n bẹ laarin awọn.

Bakan naa lo fi ẹsun kan Dino Melaye ninu fọnran ohun naa pe oloselu naa n sẹ nipa ajọsepọ awọ, fun awọn olulufẹ tuntun to sẹsẹ ni, to si darukọ Omoburty.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa, gbajumọ ọmọ jayejaye naa, Sẹnetọ Dino Melaye ti fesi pe ko si ajọṣepọ ifẹ kankan laarin oun ati Iyabọ Ojo tabi Biọdun Okeowo, ti ọpọ mọ si Omoborty.

Awọn oju opo ayelujara kan ti kọkọ gbe sita ṣaaju pe Dino Melaye ati Iyabọ Ojo jijọ n ṣe wọlewọde tẹlẹ, ki oṣere ẹgbẹ rẹ, Ọmọborty to jaa gba mọọ lọwọ.

Aworan oju opo instagram Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Screenshot/instagram

Bakan naa ni iroyin sọ pe osere tiata kan Olabisi ọmọ Logbalogba, ti ọmọ kan fun Sẹnetọ Dino Melaye amọ ti onitọun kọ pe ko ri bẹẹ.

Sẹnetọ Melaye ni "Lori irọ" ni gbogbo iroyin naa pẹlu fọnrọn ohun ti Iyabọ Ojo ti n sọ pe irọ ni Dino n pa kiri fawọn obinrin to ba kọ ẹnu ifẹ si pe oun Iyabọ lo n le Dino kiri lati fẹ oun.

"O ga oooo. Dino fẹ fẹ A sile, Dino fun B loyun, Dino n ṣe aayan ifẹ pẹlu C, gbogbo rẹ lori irọ ni....haba!!!! Ẹ maa daamu jina, maa fẹyawo laipẹ, koboko ni yoo si fi le gbogbo yin danu. Ẹyin alainiṣẹ gbogbo."

Ọrọ bi edeaiyede kii se lori Dino Melaye.

Fun ọdun mẹwaa ni oun pẹlu Tokunbọ Melaye fi fẹra ni lọkọlaya, ki tirela to gba aarin wọn kọja lẹyin ọmọ mẹta.

Àkọlé fídíò, Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda