Baba Ijesha: TAMPAN ní Iyabo Ojo, Nkechi Blessing àtàwọn míì tó bá tàbùkù ẹgbẹ́ rugi oyin

Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/nkechiblessingsunday/Instagram

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹ itan sare.

Idi ree ti ẹgbẹ to n sakoso awọn osere tiata lagbo ede Yoruba, TAMPAN, fi n ke tan tan pe se n fi ewe ọmọ mọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan leti.

Ẹgbẹ TAMPAN atawọn agbaagbaa oludari ere tiata sekilọ yii lasiko ipade akọroyin ti wọn se lọjọ Abamọta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ naa, ti agba osere tiata kan, Jide Kosoko gbẹnu rẹ sọrọ ni lati akoko yii lọ, oun ko ni fara mọ iwa ọyaju lati ọdọ ọmọ bẹ naa mọ.

Ẹgbẹ TAMPAN wa ke si Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing, ti wọn jẹ oserebinrin pe ki wọn fopin si iwa ifẹsunkan ni lọna aitọ, eebu ati itabuku ẹni, ti wọn n hu si ẹgbẹ ọhun.

Awọn agba osere tiata

Oríṣun àwòrán, @goldmynetv

"Wọn ti pe akiyesi ẹgbẹ TAMPAN si awọn iwa ibanilorukọjẹ tawọn eeyan kan ti ko ni iwa ikora ẹni nijanu, ti wọn si ro pe awọn ga ju ofin ẹgbẹ lọ, n hu.

A n wo ọpọ iwa itabuku ẹni ti Iyabo Ojo n sọ si ẹgbẹ wa ati agbo osere tiata lapapọ.

Gẹgẹ bi i ara awọn to da isẹ yii silẹ, a ko le kawọ gbera, ka si jẹ ki wọn maa paroko ti ko dara ransẹ si gbogbo aye lai da wọn lẹkun.

Ohun to n sẹlẹ yii ti nipa ti ko dara lori orukọ rere wa, to si le tẹsiwaju lati sakoba fawọn osere tiata ti ko ni sna isẹ aje miran yatọ si ere tiata Yoruba.

Nkechi Blessing naa ti dara pọ mọ iwa buruku yii to n tako ẹgbẹ wa, ta si n sọ pe O to gẹẹ."

Jide Kosoko, gẹgẹ bi ọmọ igbimọ majẹobajẹ fun ẹgbẹ TAMPAN ati agba osere tiata ni ede Yoruba, wa kilọ fun Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing atawọn miran to n huwa bii tiwọn.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

"Tẹ ba ro pe gbogbo aseyọri yin ati ohun tẹ da loni, kii se lati ipasẹ agbo ere tiata Yoruba ni, o sa yẹ kẹ mọ pe ẹka yii fun yin ni anfaani ati ayika to dara lati di ohun tẹ da lonii.

Abuku si ẹnikan jẹ abuku si gbogbo wa, a si ke si awọn ẹka ẹgbẹ tiata miran lati sugba wa tẹ ba tẹsiwaju lati maa tabuku wa.

A si fi n da yin loju pe tẹ ba tun tapa si ẹgbẹ wa, ẹ ko ni lọ laijiya."

Lara awọn agbaagba elere tiata miran to tun wa nibi ipade akọroyin naa ni Adebayo Salami, ti ọpọ mọ si ọga Bello, Ebun Oloyede, Bolaji Amusan ati Yinka Quadri.

Àkọlé fídíò, yyyy

Ero Olofana kii se ero ẹgbẹ TAMPAN

Bakan naa ni ẹgbẹ TAMPAN ti fesi si ọrọ kan ti Oloye Aderemi Adedeji, ti wọn tun n pe ni Olofana sọ nipa ọrọ Baba Ijesha.

Olofana lo kede fawọn akọroyin pe ko si agba osere tiata lobinrin kankan ti yoo ni oun de ipo giga lai jẹ pe o ti ni ibalopọ pẹlu eeyan kan ninu ẹgbẹ naa.

Amọ ẹgbẹ TAMPAN, ninu atẹjade kan to fisita kede ni ero agba osere naa kii se ero ẹgbẹ naa rara.

"Ẹgbẹ tiwa kii fara mọ iwa ibalopọ laibikita, bẹẹ ni kii se ara ilana ẹgbẹ wa. Bi agbaagba meji ba gba lati ni nnkan papọ, eyi ko tumọ si pe ohun to n sẹlẹ kaakiri ninu ẹgbẹ tabi agbo osere ni eleyi.

Àkọlé fídíò, Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda

Ko si ni akọsilẹ wa pe awọn osere binrin gbọdọ ni ibalopọ pẹlu akẹẹgbẹ lọkunrin tabi awọn ọga wọn, ki wọn to le debi giga ninu ẹgbẹ."

Atẹjade naa wa rọ awọn eeyan to ni iru eyi lero lati yipada nitori asise gbaa ni.

TAMPAN ni awọn ohun to se pataki ki osere tiata kan to de ipo giga ni talẹnti rẹ, idanilẹkọ to gba ati afojusun lati mọ ohun to nwa.