TB Joshua: Láàrin July 5 sí 11 ní ètò ìsìnkú olóògbé náà yóò fi wáyé

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries/Instagram

Mọlẹbi oloogbe Wolii TB Joshua to dagbere faye laipẹ yii ti kede ọjọ isinku ati bi ilana isinku oloogbe naa yoo se lọ.

Atẹjade kan ti aya oloogbe TB Joshua, Evelyn fisita lorukọ igbimọ oludari ijọ Synagogue lo sisọ loju ilana isinku naa.

Gẹgẹ bi ilana isinku naa se lọ, bi eto isinku oloogbe TB Joshua ba se n lọ, ni wọn yoo maa se afihan rẹ lori ayelujara ati loju opo Tẹlifisan ijọ naa, Emmanuel TV.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ilana isinku TB Joshua yoo se lọ ree:

Ọjọ Karun osu Keje ọdun 2021: Tito lọwọọwọ pẹlu abẹla

Atẹjade ilana isinku naa ni ọjọ karun osu Keje ọdun 2021 ni tito lọwọọwọ pẹlu abẹla yoo waye ni deede aago mẹfa abọ irọlẹ.

Ọjọ Kẹfa osu Keje ọdun 2021: Isin Imọyi

Laarin ọjọ meji yii ni isin imọyi fun oloogbe yoo waye, tawọn eeyan yoo si maa sọ ohun ti wọn mọ nipa oloogbe TB Joshua atawọn ohun to gbe ile aye se.

Aago mẹwa aarọ si meje alẹ ni isin imọyi yii yoo waye.

Ọjọ Keje osu Keje ọdun 2021: Isin alẹ onigbagbọ ati asalẹ iyin

Nigba to ba di ọjọ Keje osu Keje ọdun 2021, ni wọn yoo se isin alẹ orin onigbagbọ ati asalẹ iyin fun oloogbe.

Aago mejila ọsan ni isin naa yoo waye.

Ọjọ Kẹjọ osu Keje ọdun 2021: Titẹ oku ni itẹ ẹyẹ

Ọjọ Kẹjọ osu Keje ọdun 2021 ni wọn yoo tẹ oku oloogbe TB Joshua naa ni itẹ ẹyẹ .

Aago mọkanla aarọ si marun irọlẹ ni titẹ oloogbe naa nitẹ ẹyẹ yoo fi maa waye.

Ilana isinku Oloogbe TB Joshua

Oríṣun àwòrán, SCOAN

Ọjọ Kẹsan osu Keje ọdun 2021: Isinku oloogbe

Ọjọ Kẹsan osu keje ọdun 2021 ni wọn yoo tẹ oku TB Joshua sile ikẹyin, ti wọn yoo si fi ara rẹ fun ilẹ.

Aago mẹwa aarọ ni eto naa yoo maa waye.

Ọjọ Kọkanla osu Keje ọdun 2021: Isin idupẹ

Isin idupẹ fun isinku oloogbe TB Joshua yoo waye ni ọjọ Aiku, ọjọ Kọkanla osu Keje ọdun 2021

Deede aago mẹsan si mọkanla aarọ ni isin idupẹ naa yoo maa waye.

Ijọ naa wa kede pe ilu Eko ni wọn yoo ti se gbogbo eto isinku yii, ti wọn yoo si tun sin oloogbe TB Joshua silu Eko bakan naa.