TB Joshua burial: Mo tan àbẹ́là láti fi gbàdúrà fún ẹ̀mí T. B Joshua - Páṣítọ̀ kan ni Israel

Oríṣun àwòrán, others
Pasitọ ìjọ Church of Nativity, nilu Bethlehem lorilẹ-ede Israel, William Ghattas, ti ṣe idaro gbajugbaja wolii, ọmọ Naijiria to ku laipẹ yii, Temitope Joshua, ni ara ọtọ.
Ni ṣe ni pasitọ naa tan abẹla lati fi ṣọ̀fọ̀ akẹẹgbẹ rẹ to lọ.
Ninu ọrọ kan to kọ ni Ọjọru, Pasitọ Ghattas sọ pe oun tan abẹla naa, lati fi gbadura fun oloogbe T. B Joshua ni.
- Àwọn ọlọ́pàá máa ń yọ Baba Ijesha jáde látimọ́lé lálaalẹ́ - Princess
- Olùwọ́de EndSARS bímọ tuntun nínú ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó ti lo oṣù mẹ́jọ ní àhámọ́
- Èèyàn mẹ́ta ló kú níbi afẹ́fẹ́ gáàsì tó jó Chinese restaurant lágbègbè Sheraton ní Ikeja l'Eko - LASEMA
- Mi ò pinu láti du ipò òṣèlú kankan ní Naijiria - Muhammadu Sanusi II
Ọjọ Satide, ọjọ karùn-ún, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni Joshua ku, lẹni ọdun mẹrindinlọgọta.
William Ghatta, to jẹ alamojuto ìjọ Nativity, ni Bethlehem, tan abẹla naa ni aarin gbùngbùn ilé ìjọsìn naa, nibi ti wọn bi Jesu si, pe ki ẹ̀mí rẹ ko sun re.
Saaju asiko ni sọọsi T. B Joshua, Synagogue Church of All Nations, SCOAN, ti kọkọ kede pe lẹyin ti wolii naa kú àwọn ololufẹ rẹ lori ayelujara Facebook ti lé si pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta, ti ẹgbẹgbẹrun eeyan l'agbaye si n daro ikú rẹ.
Wọn ni ọpọ lo ṣe iṣọ oru adura pẹlu titan abẹla, nitori oloogbe ọhun.
Ọjọ karun-un si ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2021 ni ìjọ SCOAN kede pe eto ayẹyẹ isinku oloogbe yoo waye "
- Bí ọkùnrin kan ṣe pa ìya rẹ̀ tó sì tún sè é sí ọbẹ̀ jẹ, ohun tójú rẹ̀ rí rèé
- Sunday Igboho ní agbébọn tí kò bá kúrò nínú igbó Yorùbá láti ọjọ́ Aje rugi oyin
- Nkan n bẹ! Páṣítọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ pa torí pé ó ń yan àlè
- Wo ikú tó pa Kenneth Kaunda, Ajìjàgbara fún òmìnira Áfíríkà tó gbẹ̀yìn
- Iyabo Ojo bẹ̀rẹ̀ ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ pẹ̀lú máníjà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn olè jíjà
Ki lo ti ṣélẹ sẹyin?
Ìjọ Synagogue ti kéde ọjọ́ ìsìnkú TB Joshua pẹ̀lú ibi tí wọn yóò sin ín sí

Oríṣun àwòrán, others
Ijọ Synagogue Church of All Nations nilu Eko ti kede akoko ati ibi ti wọn yoo sin olusọaguntan wọn to papoda laipẹ yii, Pasitọ Temitọpẹ Balogun Joshua si.
Ninu atẹjade kan eyi ti wọn fi sita lọjọ Aje, wọn ni inu ayika olu ile ijọsin naa to wa nilu Eko ni wọn yoo sin wolii TB Joshua si.
"A n gbaradi fun eto isin ọlọsẹ kan ti yoo bẹrẹ ni ọjs karun un si ikọkanla ni iranti igbe aye Wolii TB Joshua."
Atẹjade naa tun tẹsiwaju pe, "A o sin si ile ijọsin The Synagogue, Church of All Nations (SCOAN) nilu Eko"
Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Pasitọ TB Joshua ki o to jade laye lọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2021 nigba to ku ọjọ diẹ si ọjọ ibi rẹ.















