Bobrisky: Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí náà pọ̀ àmọ́ n kò kábàámọ̀ pé mo ṣe é

Oríṣun àwòrán, bobrisky222
Gbajumọ akọ to n mura bii abo, Idris Okunneye, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, ti kede pe wọn tun ti gbe oun digba-digba lọ sile iwosan.
Bobrisky, ẹni to kede isẹlẹ laa loju opo Instagram rẹ lọjọ Aje, lo se isẹ abẹ idi nla, ti wọn si fa ọra kuro ni inu ikun rẹ, itan ati igegeru.
Awọn ọra yii ni wọn lẹ mọ ibadi rẹ, ko le tobi si, ti yoo si dabi idi nla ta mọ awọn obinrin mọ.
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Wo ìdí to fi gbọdọ̀ yàgò fún Bobrisky, akọ tó ń ṣe bíi abo
- Mo fẹ́ di obinrin to dára júlọ lágbàyé-Bobrisky
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Bí àwọn ọ̀tá mi bá jẹ ilá àti ẹ̀bà tán, itẹ́ òkú ní wọn yóò ti fọwọ́ - Bobrisky
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
Bobrisky, ẹni to ti kede saaju pe oun n jẹ irora to lagbara lati ipasẹ isẹ abẹ naa, tun salaye pe wọn ti gbe oun pada lọ sile iwosan lọjọ Satide.

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram
"Wọn tun ti gbe mi digba-digba pada sile iwosan to sun mọ mi ni alẹ ọjọ meji sẹyin nitori irora nla ti mo n jẹ tori isẹ abẹ idi ti mo se.
Amọ n ko kabamọ rara! Laipẹ ni n maa ju idi mi...bi o tilẹ jẹ pe mo ti n reti tẹlẹ pe maa jẹ irora tori isẹ abẹ naa.
Lasiko yii, owo ti maa ma gba yoo lọ soke si, o si yẹ kẹ ri idi mi bayii, o ti tobi daadaa si, ti yoo si maa dawọn eeyan lọrun."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Àsìkò tó fún Buhari láti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ìgbìmọ̀ Àgbààgbà Yorùbá
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC
- Sunday Igboho kan sárá sáwọn ọmọ Yorùbá tó wọ́de lọ́jọ́ Sátidé, ṣùgbọ́n kò sọ ìdí tí kò fi jáde
Bakan naa ni Bobrisky tun sisọ loju rẹ pe o kuku nidi ti oun fi n se isẹ abẹ idi naa nitori kii se oju lasan ni oun fi n se.
O salaye pe oun n fara da irora ọhun lati sisẹ abẹ idi yii nitori ololufẹ oun, tii se olowo rẹpẹtẹ ni, ki oun le tubọ maa da lọrun.

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram
Gbajumọ onisowo ipara naa fikun pe eyi yoo tubọ mu ki ololufẹ oun naa tubọ maa na owo rẹpẹtẹ fun oun ni.
Ikede Bobrisky yii si ti n mu kawọn oloufẹ rẹ fesi si ọrọ naa, bi awọn kan si se n ki pe o pẹlẹ, tori irora naa, ni awọn miran n sọ pe o daa bẹẹ fun.

Bobrisky fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn tó ń ro ikú rò ó torí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe

Oríṣun àwòrán, bobrisky222
A ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe, gbajugbaja ọkunrin to maa n mura bii obinrin, Idris Okunneye, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, ti sọrọ lori iṣẹ abẹ to lọ ṣe si ibadi rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ṣaaju ni Bobrisky ti kọkọ n wa ẹkun mu loju opo Snapchat rẹ, nibi to ti ṣalaye pe inu irora nla ni oun wa nitori iṣẹ abẹ naa, eyii to mu ki ọpọ awọn ololufẹ rẹ bẹrẹ si n kaanu rẹ.
Ṣugbọn o dabi pe ẹkọ ti n fi oju mumu han fun Bobrisky bayii to tun ti sọrọ loju opo Instagram rẹ, nibi to ti ṣalaye fun awọn ololufẹ rẹ nibi to ba iṣẹ abẹ naa de.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tó mú kí àyájọ́ June 12 ṣe pàtàkì fún Nàíjíríà
- Kudirat Abiola: Akọni obìnrin tó jẹ́ ọ̀wọ̀n ìrántí fún àyájọ́ ìjọba alágbádá
- Àwọn asọni di Òtòṣì àti Aláìmọ̀kan là ń bá jà - Tinubu
- ₦324bn la pín fún 136,000 oníṣòwò ké kè ké lásìkò ìgbélé Covid-19 - Buhari
- Wo ibi tí ìpalẹ̀mọ́ fún ìwọ́de June 12 dé dúró ní Nàíjíríà àti òkè òkun
- Ọ̀rọ̀ díẹ̀ ati ìgbésẹ̀ akin lá máa gbé báyìí lórí ọ̀rọ̀ Nàíjíríà - Obasanjo
- Wo ipa mánigbàgbé táwọn ààrẹ ní sáà ìjọba alágbádá kẹ́rin ṣe
- Wo àwọn ààrẹ alágbádá tó ti jẹ ní Nàìjíríà láti 1960 di àkókò yìí
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ara rẹ ti n da ṣaka lẹyin iṣẹ abẹ naa, awọn irora to farada ṣaaju si ti n dinku.
O ni laipẹ ni oun yoo fi ara oun han fun awọn toun ki wọn le foju ganni ayipada to de ba ibadi rẹ lẹyin iṣẹ abẹ naa.

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram
Ninu atẹjade ọhun lo tun ti fi ẹmi imoore han si ọkan pataki lara awọn ọrẹ to duro tii lasiko ti wọn n ṣiṣẹ abẹ naa.
O ni "Mo dupẹ lọwọ ọrẹ mi pataki to duro ti mi lasiko ti mo n ṣiṣẹ abẹ lọwọ, mo mọ pe ifẹ to ni si mi ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu owo.
Sugbọn o jẹ ifẹ atinu ọkan wa. Mo dupẹ lọwọ rẹ fun ibadọrẹpọ rẹ lati nnkan bi ọdun marun un sẹyin wa."
Ẹwẹ, lẹsẹ kan naa ni Bobrisky tun bu ẹnu ẹtẹ lu awọn eeyan kan, to fi ẹsun kan pe ifẹ oju lasan ni wọn ni si oun.
Bobrisky ni ọpọ eeyan lo n fẹ ki oun ku lasiko iṣẹ abẹ ti oun ṣe, ṣugbọn awọn eeyan kan naa lo n sọ pe awọn n saaro oun lori ayelujara.
- Orílẹ̀-èdè Amẹrika ké sí Naijiria láti fòpin sí fifi òfin de Twitter
- Àwọn tí a jọ ń se ìjọba ní Nàìjíríà sisẹ́ gba ipò wọn lábẹ́ ìjọba mi ni- Aarẹ Buhari
- Wo àwọn orílẹ̀èdè mẹ́rin l‘Afrika tó ṣetán láti ra iná ìjọba láti Naijiria
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Pańpẹ́ ọba mú pàsítọ̀, babaláwo àti àwọn mẹ́ta tí wọ́n ká ara ènìyàn mọ́ lọ́wọ́
Gẹgẹ bo ṣe sọ, irufẹ awọn eeyan bẹẹ ko ṣe fọkan tan nitori ifẹ oju lasan ni wọn ni si oun.

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram
O wa fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe oun ṣi n pada bọ lori ayelujara laipẹ ati pe ipadabọ Abija oun naa yoo lekenka.
O ni inu oun dun pe oun ṣe iṣẹ abẹ ki ara oun le ri bi oun ṣe fẹ ko ri, eyii si mu inu oundun gidi.
Yatọ si iṣẹ abẹ to ṣe, Bobrisky tun sọ pe oun ti ṣetan lati na owo ti iye rẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna ogoje naira lori ọkọ ayọkẹlẹ tuntun.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe oun yoo ra ile tuntun kan ti iye rẹ to irinwo miliọnu naira.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo awọn afojusun wọnyi ni yoo mu ṣe titi oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Bobrisky pari ọrọ rẹ pe ara ọtọ ni oṣu Kẹjọ naa yo jẹ nitori awọn ohun meremere ti oun ti ni lọkan lati ṣe.



















